DECEMBER 17, 2019
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà fún Arákùnrin Alushkin, Wọ́n sì Ń Gbé Àwọn Ará Márùn-Ún Míì Yẹ̀ Wò Lọ́wọ́
Ní àárọ̀ Friday, December 13, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Leninsky ní ìlú Penza dájọ́ pé arákùnrin Vladimir Alushkin jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fí kàn án, wọ́n sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún-un. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́ tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan náà kan ìyàwó rẹ̀ Tatyana, àtàwọn mẹ́rin míì. Ilé ẹjọ́ ṣì ń ṣàyẹ̀wò àwọn márààrún (àwọn arákùnrin mẹ́ta àtàwọn arábìnrin méjì) lọ́wọ́, tí wọ́n á sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fún wọn bí wọn kò bá pa òfin ilé ẹjọ́ mọ́. Àwọn ará mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wá láti ìlú Penza yìí máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí.
Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ní oṣù July 15, 2018, àwọn ọlọ́pàá bíi méjìlá tó fi nǹkan bojú tí wọ́n sì gbébọn lọ́wọ́ já wọ ilé Vladimir Alushkin wọ́n sì mú un lọ. Nǹkan bí wákàtí mẹ́rin ni wọ́n fi tú inú ilé rẹ̀, wọ́n kó àwọn fóònù rẹ̀, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé rẹ̀, Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, wọ́n lọ ṣàyẹ̀wò ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà márùn-ún míì, wọ́n sì kó nǹkan bí ogójì (40) àwọn ará lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Àwọn ọlọ́pàá àdúgbò kọ́kọ́ fi Arákùnrin Alushkin sí àtìmọ́lé kan ládùúgbò fún ọjọ́ méjì kó tó wá di pé Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Pervomayskiy ní ìlú Penza ní kó lọ ṣẹ̀wọ̀n fún oṣù méjì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n míì títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì ni ilé ẹjọ́ agbègbè yìí fi kún iye ọjọ́ tí Vladimir Alushkin lò lẹ́wọ̀n láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ rárá. Lẹ́yìn tó lo nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́wọ̀n, wọ́n ní kó pa dà sílé àmọ́ kó gbọdọ̀ jáde nínú ilé rẹ̀. Ipò yìí ló wà títí tí ilé ẹjọ́ fí dá a lẹ́bi ní December 13.
Yàtọ̀ sí Arákùnrin Alushkin, àwọn arákùnrin mẹ́ta tó wà lára àwọn márùn-ún tí wọ́n fẹ̀sùn yìí kan ni Arákùnrin Vladimir Kulyasov, Andrey Magliv, àti Denis Timoshin. Wọ́n sọ pé wọn kò gbọdọ̀ jáde nílé títí ìwádìí àti ìgbẹ́jọ́ wọn fi máa parí. Wọ́n tún ṣòfin lóṣù February 2019 pé àwọn arábìnrin méjì tó kù, ìyẹn Arábìnrin Tatyana Alushkina àti Galiya Olkhova kò gbọdọ̀ jáde kúrò nílùú, ó sì lójú àwọn tí wọ́n ilé ẹjọ́ gbà wọ́n láyè láti bá sọ̀rọ̀.
Ní August 2019, Àjọ Tó Ń Rí sí Títini Mọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé (WGAD) tẹ ìwé olójú-ewé méjìlá kan láti ta ko bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fẹ̀sùn kan Arákùnrin Alushkin tí wọ́n sì tún tì í mọ́lé. Àjọ náà sọ pé “bí wọ́n ṣe gbé Arákùnrin Alushkin tí wọ́n sì tì í mọ́lé kò bófin mú, wọn kò sì gbọdọ̀ bá a ṣe ẹjọ́ kankan mọ́.” Àjọ náà tún tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí pé “tí wọ́n bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yanjú, àfi kí wọ́n dá Arákùnrin Alushkin sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” Nígbà tí agbẹjọ́rò àwọn ará mẹ́fà tó kù tó wà nílùú Penza sì máa sọ̀rọ̀, orí ohun tí àjọ tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí sọ ló gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ náà ní December 13, adájọ́ sọ pé òfin tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe lọ́dún 2017 làwọn máa tẹ̀ lé, òfin náà sì ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tún gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn mọ́ lórílẹ̀ èdè náà. Adájọ́ sọ pé òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà yìí lágbára ju ohun tí àjọ WGAD sọ lọ.
Lọ́dún yìí, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti dá àwọn ará méjìdínlógún (18) lẹ́bi, wọ́n sì ti ju mẹ́sàn-án lára wọn sẹ́wọ̀n. Èyí tó ju ogójì (40) lọ nínú àwọn ará wa ló wà látìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn, tí àwọn mọ́kàndínlógún (19) míì kò sì gbọdọ̀ jáde nílé. Jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) àwọn ará tí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.
Ká sòótọ́, bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn ará wa yìí kò dùn mọ́ wa nínú, síbẹ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kò yà wá lẹ́nu. Bíbélì ti sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ó sì tún sọ pé Jèhófà máa fìfẹ́ ràn wá lọ́wọ́. A gbàdúrà pé kí ‘ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, bà lé wọn.’—1 Pétérù 4:12-14.