Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 23, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Arákùnrin Dennis Christensen Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Arákùnrin Dennis Christensen Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Ní June 23, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Lgovskiy tó wà ní Kursk dá Arákùnrin Dennis Christensen sílẹ̀ kí ọdún tí wọ́n ní kó lò lẹ́wọ̀n tó pé. Àwọn tó pe ẹjọ́ náà ní kí adájọ́ gba owó ìtanràn lọ́wọ́ Arákùnrin Christensen dípò ọdún tó kù tó yẹ kó lò lẹ́wọ̀n. Adájọ́ wá ní kó san nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ náírà (ìyẹn $5,759 owó Dọ́là). Ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́wàá tí wọ́n kéde ìdájọ́ yìí ni Arákùnrin Christensen tó máa làǹfààní láti lọ bá ìyàwó rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àṣeyọrí yìí!