Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Aleksandr àti Anna Solovyev

JULY 5, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan Ní Rọ́ṣíà Dájọ́ Pé Arákùnrin Aleksandr Solovyev Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kàn Án

Ilé Ẹjọ́ Kan Ní Rọ́ṣíà Dájọ́ Pé Arákùnrin Aleksandr Solovyev Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kàn Án

Ní Thursday, July 4, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ordzhonikidzevskiy ní agbègbè Perm’ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kéde pé Arákùnrin Aleksandr Solovyev jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì ní kó san ìtanràn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (4,731) owó dọ́là.

Ìrọ̀lẹ́ May 22, 2018 ni wọ́n fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Solovyev ní ibùdókọ̀ ojú irin nígbà tí òun àti Anna ìyàwó rẹ̀ ń bọ̀ láti ìrìn-àjò tí wọ́n lọ lórílẹ̀-èdè míì. Àwọn ọlọ́pàá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sọ́wọ́ Arákùnrin Solovyev, wọ́n sì fi í sátìmọ́lé fúngbà díẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá tún mú Arábìnrin Solovyev, àmọ́ ọkọ̀ tí wọ́n fi gbé e yàtọ̀ sí ti ọkọ̀ ẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá tú ilé wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ní gbogbo òru, wọ́n sì kó àwọn fọ́tò wọn, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti oríṣiríṣi Bíbélì.

Wọ́n da ìbéèrè bo Arábìnrin Solovyev, lẹ́yìn náà wọ́n tú u sílẹ̀, wọn ò sì fẹ̀sùn kàn án. Àmọ́, wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Solovyev, nígbà tó sì di May 24, wọ́n sé e mọ́lé títí di November 19, 2018. Kó tó dìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀, wọ́n ò fún un lómìnira láti jáde bó ṣe fẹ́.

Agbẹjọ́rò Arákùnrin Solovyev máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un. Wọ́n tún ti kọ̀wé sí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Tó Ń Gbógun Ti Fífini Sátìmọ́lé Lọ́nà Tí Kò Bójú Mu.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti láwọn orílẹ̀-èdè míì ń le sí i, a ò ní jẹ́ káwọn alátakò yìí “kó jìnnìjìnnì bá wa lọ́nàkọnà.” Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fara dà á títí táyé tuntun tá à ń retí fi máa dé.—Fílípì 1:28