OCTOBER 8, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Dá Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́fà, Wọ́n sì Ní Kí Wọ́n Lo Iye Ọdún Tó Yẹ Kí Wọ́n Fi Ṣẹ̀wọ̀n Nílé
Ní October 8, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Zasviyazhsky tó wà nílùú Ulyanovsk dá ẹjọ́ àwọn ará wa yìí, ìyẹn Arákùnrin Aleksandr Ganin, Arákùnrin Khoren Khachikyan, Arákùnrin Andrey Tabakov, Arákùnrin Mikhail Zelenskiy, Arákùnrin Sergey Mysin àti Nataliya ìyàwó ẹ̀. Wọ́n ní kí wọ́n lo àkókò tó yẹ kí wọ́n lò lẹ́wọ̀n nílé, káwọn agbófinró sì máa ṣọ́ wọn. Iye ọdún tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn máa lò yàtọ̀ síra láti ọdún méjì àti oṣù mẹ́fà sí ọdún mẹ́rin. Ó túmọ̀ sí pé àwọn ará wa yìí ò ní lọ sẹ́wọ̀n.