Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Khasan Kogut àti Yekaterina ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ náà

SEPTEMBER 10, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Dá Ẹjọ́ Arákùnrin Khasan Kogut

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Dá Ẹjọ́ Arákùnrin Khasan Kogut

Ní September 10, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Berezovsky lágbègbè Kemerovo dá ẹjọ́ Arákùnrin Khasan Kogut. Dípò táá fi lọ sẹ́wọ̀n, ilé ẹjọ́ ní kó lo ọdún méjì àtààbọ̀ nílé, wọ́n sì ní kí wọ́n máa ṣọ́ ọ ní gbogbo àsìkò yẹn. Ṣe ni Arákùnrin Kogut ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé òun máa lè wà pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọkùnrin òun tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ.