Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 4, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Dẹ́bi fún Arákùnrin Kim àti Arákùnrin Polevodov

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Dẹ́bi fún Arákùnrin Kim àti Arákùnrin Polevodov

Ní February 4, 2020, Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy tó wà ní Khabarovsk dẹ́bi fún Arákùnrin Stanislav Kim àti Arákùnrin Nikolay Polevodov. Dípò tí wọ́n fi máa fi àwọn méjèèjì sẹ́wọ̀n fún ọdún méjì, ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n wà nílé, àmọ́ wọ́n á máa ṣọ́ wọn fún gbogbo àsìkò yẹn, wọn ò sì ní lómìnira. Àwọn arákùnrin yìí pinnu láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí. Ilé ẹjọ́ míì nílùú Khabarovsk tún fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin yìí pé wọ́n jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn. Àmọ́, wọn ò tíì mú ọjọ́ tí wọ́n máa dá ẹjọ́ yìí.