Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Arábìnrin Silaeva, Arábìnrin Shamsheva, Arákùnrin Khokhlov àti Arákùnrin Zhinzhikov nílé ẹjọ́ ní October 28, 2020

OCTOBER 28, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Fọwọ́ Sí I Pé Àwọn Arákùnrin Méjì àti Arábìnrin Méjì Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kàn Wọ́n

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Fọwọ́ Sí I Pé Àwọn Arákùnrin Méjì àti Arábìnrin Méjì Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kàn Wọ́n

o Ní October 28, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Bryansk fọwọ́ sí ìdájọ́ tílé ẹjọ́ kọ́kọ́ ṣe lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Vladimir Khokhlov, Arákùnrin Eduard Zhinzhikov, Arábìnrin Tatyana Shamsheva àti Arábìnrin Olga Silaeva. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dá ẹjọ́ wọn, ilé ẹjọ́ ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lo ọdún kan tàbí ọdún kan àti oṣù mẹ́ta lẹ́wọ̀n. Àmọ́, wọn ò lọ sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ti lo àsìkò yẹn látìmọ́lé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdájọ́ tí wọ́n ṣe fáwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí á mú káwọn èèyàn máa fojú ọ̀daràn wò wọ́n. Àmọ́, inú wọn dùn pé wọn ò ní lọ sẹ́wọ̀n mọ́. Níbi tọ́rọ̀ sì dé yìí, àwọn alátakò ò láǹfààní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn mọ́, débi tí wọ́n á tún fi fìyà tó le jẹ wọ́n.

Kí wọ́n tó ṣèdájọ́ wọn nígbà àkọ́kọ́, Arákùnrin Vladimir Khokhlov àti Arákùnrin Eduard Zhinzhikov ti lo 316 ọjọ́ látìmọ́lé, Arábìnrin Tatyana Shamsheva àti Arábìnrin Olga Silaeva sì ti lo 245 ọjọ́ látìmọ́lé. Lẹ́yìn táwọn arábìnrin méjèèjì kúrò látìmọ́lé, wọ́n fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò nínú fídíò Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2020 #5. Nínú fídíò yẹn, wọ́n ní ohun tó mú káwọn máa láyọ̀ báwọn ṣe ń fara dà á ni báwọn ṣe ń gbàdúrà, táwọn ń ka Bíbélì, táwọn sì ń mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fáwọn.