Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Anatoliy Tokarev níta ilé ẹjọ́ ní August 2020

OCTOBER 23, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Anatoliy Tokarev San Owó Ìtanràn

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Anatoliy Tokarev San Owó Ìtanràn

ÌRÒYÌN LỌ́Ọ́LỌ́Ọ́ | Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Wọ́gi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Ní November 30, 2021, ilé ẹjọ́ Sixth General Jurisdiction Court of Cassation wọ́gi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Arákùnrin Anatoliy Tokarev pè. Wọ́n máa ní kó san owó ìtanràn.

Ní October 23, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oktyabrsky tó wà ní Kirov dẹ́bi fún Anatoliy, wọ́n sì ní kó san owó ìtanràn nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ náírà ($6,552 U.S.). Ó láǹfààní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láàárín ọjọ́ mẹ́wàá.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Tokarev sọ kẹ́yìn kó tó kúrò nílé ẹjọ́, ó fìgboyà sọ pé: “Ohun táwọn agbófinró ń dọ́gbọ́n sọ nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn mí ni pé: ‘A fẹ́ kó o sọ pé o ò sin Ọlọ́run mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ . . . a máa fìyà tó le jẹ ẹ́ níwájú gbogbo èèyàn.’ . . . Olúwa mi, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ yìí, mo ti sọ fún ilé ẹjọ́ pé mi ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀, ohun kan náà ni màá tún sọ lónìí. . . . Lóòótọ́, kò sẹ́ni tá gbọ́ pé wọ́n fẹ́ fi òun sẹ́wọ̀n tàbí pa òun bí wọ́n ṣe ń halẹ̀ mọ́ èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kù, tẹ́rù ò ní bà á. Bí wọ́n sì ṣe pè mí ní agbawèrèmẹ́sìn láìrú òfin ìjọba ti bà mí lórúkọ jẹ́. Síbẹ̀, Olúwa mi, mi ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀, kí n má bàa kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀.”