Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 28, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Yevgeniy Spirin San Owó Tó Lé Ní Mílíọ̀nù Méjì Ààbọ̀ Náírà

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Yevgeniy Spirin San Owó Tó Lé Ní Mílíọ̀nù Méjì Ààbọ̀ Náírà

Ní July 28, 2020, ilé ẹjọ́ tó wà nílùú Furmanovsky ní agbègbè Ivanovo sọ pé Arákùnrin Yevgeniy Spirin jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Àwọn tó pè é lẹ́jọ́ ní kí ilé ẹjọ́ fi Arákùnrin Spirin sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje. Àmọ́, ilé ẹjọ́ ní kó san owó ìtanràn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ náírà ($6,920 U.S.) dípò kó lọ sẹ́wọ̀n. Arákùnrin Spirin máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí.