Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Rán Arákùnrin Alushkin Lọ sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Rán Arákùnrin Alushkin Lọ sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Ní December 13, 2019, ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ Arákùnrin Vladimir Alushkin, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà. Ojú ẹsẹ̀ níbẹ̀ ni wọ́n ti fí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́ tí wọ́n sì mú un lọ. Arákùnrin Alushkin máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí.