Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 24, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ní Kí Arákùnrin Sergey Ledenyov Lo Ọdún Méjì Tó Yẹ Kó Lò Lẹ́wọ̀n Nílé

Ilé Ẹjọ́ Ní Kí Arákùnrin Sergey Ledenyov Lo Ọdún Méjì Tó Yẹ Kó Lò Lẹ́wọ̀n Nílé

Ní November 24, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Petropavlovsk-Kamchatskiy tó wà lágbègbè Kamchatka dá ẹjọ́ Arákùnrin Sergey Ledenyov. Wọ́n ní kó lo ọdún méjì tó yẹ kó lò lẹ́wọ̀n nílé, káwọn agbófinró ṣì tún máa ṣọ́ ọ fún ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn. Torí náà, kò ní sídìí fún un láti lọ sẹ́wọ̀n.

Lọ́jọ́ tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Arákùnrin Sergey kẹ́yìn, ó fìgboyà ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ní: “Jèhófà kì í ṣe orúkọ àwọn èèyàn kan, ètò kan tàbí ẹ̀sìn kan. Orúkọ Ọlọ́run ni Jèhófà. Nínú Bíbélì, Jèhófà pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ‘ẹlẹ́rìí mi.’ Torí náà, níbi àpéjọ kan tá a ṣe lọ́dún 1931, a bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ náà, ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Orúkọ yẹn sọ iṣẹ́ tá à ń ṣe, pé à ń jẹ́rìí nípa Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá, Olùgbàlà àti Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Àǹfààní ńlá nìyẹn sì jẹ́ fún èmi àtàwọn ará mi tó kù.”​—Àìsáyà 43:10.

Arákùnrin Sergey fi ìdánilójú sọ fún ilé ẹjọ́ pé: “Kò sídìí fún mi láti máa tijú, bíi pé mo ti ṣe ohun tó lòdì sófin. Mo ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn.”