Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 14, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé-Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Arákùnrin àti Arábìnrin Popov Lẹ́bi, Wọ́n Sì Ní Kí Wọ́n Sanwó Ìtanràn

Ilé-Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Arákùnrin àti Arábìnrin Popov Lẹ́bi, Wọ́n Sì Ní Kí Wọ́n Sanwó Ìtanràn

Ní February 14, 2020, Ilé-Ẹjọ́ ìlú ńlá Vilyuchinsk dá Arákùnrin Mikhail Popov àti ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popov lẹ́bi. Ilé-Ẹjọ́ ní kí Arákùnrin Mikhail Popov san 350,000 rubles ($5,508 U.S.) owó ìtanràn, wọ́n sì ní kí ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popov san 300,000 rubles ($4,722 U.S.), àmọ́ wọn ò fi wọ́n sẹ́wọ̀n rárá. Àwọn méjèèjì máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí.

Ìjọba mú Mikhail àti Yelena ní July 2018. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n máa dúró de ìdájọ́ wọn.

Láti ọdún 2019, ilé-ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlọ́gbọ̀n (28) lẹ́bi nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Nínú oṣù méjì tó kọjá nìkan, mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wọ̀nyí ni wọ́n dá lẹ́bi. Àmọ́, wọn ò tíì fi wọ́n sẹ́wọ̀n báyìí.