Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Valeriy Moskalenko nínú àhámọ́ tí wọ́n fi sí nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ láìpẹ́ yìí

AUGUST 30, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Máa Dá Ẹjọ́ Arákùnrin Moskalenko Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Máa Dá Ẹjọ́ Arákùnrin Moskalenko Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀

Adájọ́ Ivan Belykh ti ilé ẹjọ́ agbègbè Zheleznodorozhniy ní Khabarovsk ti fi ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Valeriy Moskalenko tó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta (52) sí September 2, 2019.

August 2, 2018 ni wọ́n mú Arákùnrin Moskalenko nígbà tí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba àtàwọn ọlọ́pàá tó ń kó àwọn tó ń jà ìjà ìgboro ya wọ ilé rẹ̀. Àwọn agbófinró gbọn ilé Arákùnrin Moskalenko yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ fún bíi wákàtí márùn-ún kí wọ́n tó mú un. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti tì í mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ó ti wà lẹ́wọ̀n láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún kan báyìí, ọ̀pọ̀ ló ń ronú pé wọ́n lè dá a lẹ́bi, kí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n bíi ti Dennis Christensen.

Ní December 18, 2018, a kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lórí ẹjọ́ Moskalenko v. Russia.. Ẹ̀sùn tó lé ní àádọ́ta (50) ló wà níwájú ilé ẹjọ́ yìí lòdì sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà, mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) nínú rẹ̀ sì ti dé etígbọ̀ọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

À ń fi àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà yangàn ‘nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ wọn nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ.’ Ó hàn gbangba pé Jèhófà ń tì wọ́n lẹ́yìn, ó sì ń bù kún wọn. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bá a lọ láti fún Arákùnrin Moskalenko ní okun tó nílò kó lè máa fara dà á pẹ̀lú ìdùnnú, láìka ohun tó lé jẹ́ àbájáde ìdájọ́ náà.​—2 Tẹsalóníkà 1:4.