Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Aleksey Metsger tí ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá lẹ́bi, tí wọ́n sì ní kó san owó ìtanràn nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ rèé

NOVEMBER 21, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Aleksey Metsger San Owó Ìtanràn Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Ọgọ́rùn-ún Mẹ́ta àti Ààbọ̀ Ruble (350,000 Rubles), Kò sì Gbà Pẹ̀lú Agbẹjọ́rò Ìjọba Pé Kí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Aleksey Metsger San Owó Ìtanràn Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Ọgọ́rùn-ún Mẹ́ta àti Ààbọ̀ Ruble (350,000 Rubles), Kò sì Gbà Pẹ̀lú Agbẹjọ́rò Ìjọba Pé Kí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta

Ní Thursday, November 14, 2019, ilé ẹjọ́ agbègbè Ordzhonikidzevskiy tó wà ní Perm dá Arákùnrin Aleksey Metsger lẹ́bi, kódà ó ní kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ Ruble (350,000 Rubles) ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́ta owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($5,460 U.S.) Arákùnrin yìí ni ẹni kejìlá (12) tí wọ́n dá lẹ́bi ní Rọ́ṣíà lọ́dún yìí lórí ẹ̀sùn tí kò jẹ́ òótọ́ tí wọ́n fi kàn wọ́n pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Wọ́n sì tún dá wọn lẹ́bi pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò pa ẹnikẹ́ni lára. Agbẹjọ́rò Arákùnrin Metsger máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nítorí ìdájọ́ yìí.

Ní April 25, 2019, wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Metsger nítorí pé ó sọ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Lára àwọn ẹ̀rí tí wọ́n lò lòdì sí Arákùnrin Metsger ni ọ̀rọ̀ tí òun àtàwọn kan jọ sọ nípa ẹ̀sìn táwọn yẹn sì gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́.

October 14, 2019 ni ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀, agbẹjọ́rò ìjọba sì ní kí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kò sọ Arákùnrin Metsger sẹ́wọ̀n, wọ́n ti dá arákùnrin wa míì lẹ́bi, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń fúngun mọ́ àwọn arákùnrin wa láìnídìí, a mọ̀ pé Jèhófà máa tù wọ́n nínú, á sì máa fún wọn lókun.​—Sáàmù 119:76, 161.