OCTOBER 7, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Sọ Pé Arákùnrin Yuriy Zalipayev Kò Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kàn Án!
Ní October 7, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Mayskiy tó wà ní Kabardino-Balkarian Republic kéde pé Arákùnrin Yuriy Zalipayev kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì dá a sílẹ̀ lómìnira. Àmọ́, àwọn alátakò ṣì láǹfààní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí láàárín ọjọ́ mẹ́wàá.
Àwọn alátakò fẹ̀sùn kan Arákùnrin Zalipayev pé ó ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n máa hùwà ìkà sáwọn míì. Àmọ́, àwọn èèyàn tó ju ọgbọ̀n (30) lọ ló jẹ́rìí sí i pé kò ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní ṣe ló ń gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa ka Bíbélì, kí wọ́n máa hùwà pẹ̀lẹ́, kí wọ́n sì máa finúure hàn sáwọn míì.
Ìpinnu Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè (UN Working Group on Arbitrary Detention) wà lára ohun tó mú kílé ẹjọ́ gbà pé Arákùnrin Zalipayev “ò jẹ̀bi.” Torí àìpẹ́ yìí ni àwùjọ yìí kéde pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fa wàhálà, a kì í sì í dá rògbòdìyàn sílẹ̀.
Lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìdájọ́ yẹn, Arákùnrin Zalipayev sọ pé: “Ohun tó ju èyí lọ ni ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, torí ṣe lọkàn mi balẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi ń gbọ́ ẹjọ́ náà. Inú mi dùn gan-an, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wá sílé ẹjọ́ láti jẹ́rìí sí i pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn mí.”