Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 20, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Tú Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́ta Tó Wà Látìmọ́lé Sílẹ̀ Nílùú Surgut, Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Tú Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́ta Tó Wà Látìmọ́lé Sílẹ̀ Nílùú Surgut, Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ní March 7, 2019, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Khanty-Mansiysk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wọ́gi lé ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Surgut ṣe pé kí wọ́n ti Arákùnrin Artur Severinchik mọ́lé. Wọ́n sì tú u sílẹ̀ ní March 15.

Arákùnrin Severinchik wà lára àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n jù sí àtìmọ́lé ní February 17, lẹ́yìn táwọn aláṣẹ ya wọlé àwọn èèyàn ní ìlú Surgut àti Lyantor. Ilé ẹjọ́ ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tú àwọn arákùnrin méjì tó kù sílẹ̀, ìyẹn Yevgeniy Fedin àti Sergey Loginov.

Ọ̀pọ̀ ìjọba àtàwọn oníròyìn kárí ayé ló ti gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù pàṣẹ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn dókítà ṣàyẹ̀wò ìlera Arákùnrin Loginov, torí bí wọ́n ṣe lù ú lálùbami nígbà tí wọ́n tì í mọ́lé.

A dúpẹ́ pé wọ́n tú Arákùnrin Severinchik sílẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa rántí pé bó ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ‘mìmì kan ò ní mì wọ́n.’​—Sáàmù 16:8.