Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin àti Arábìnrin Akopyan (àárín níwájú) àtàwọn míì tó wà pẹ̀lú wọn nílé ẹjọ́.

MARCH 6, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Wọ́gi Lé Ìdájọ́ Tí Wọ́n Ṣe fún Arákùnrin Akopyan Tẹ́lẹ̀ ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Wọ́gi Lé Ìdájọ́ Tí Wọ́n Ṣe fún Arákùnrin Akopyan Tẹ́lẹ̀ ní Rọ́ṣíà

Ní March 1, 2019, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Republic of Kabardino-Balkaria wọ́gi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kan fi dẹ́bi fún Arákùnrin Arkadya Akopyan. Ó ti lé lọ́dún kan tí wọ́n ti ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ó ń pín ìwé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn,” ó sì ń ‘rúná sí ìkórìíra ẹ̀sìn.’

Ilé ẹjọ́ kan ti kọ́kọ́ sọ pé kí Arákùnrin Akopyan, ẹni àádọ́rin (70) ọdún lọ ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Àmọ́ ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí wọ́gi lé ìdájọ́ ti tẹ́lẹ̀.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó mú ká borí nínú ẹjọ́ yìí, a sì bá Arákùnrin Akopyan yọ̀. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa máa fi ìṣòtítọ́ fara dà á nìṣó.—2 Tẹsalóníkà 1:4.