Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 16, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún Arákùnrin Yuriy Savelyev

Ilé Ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún Arákùnrin Yuriy Savelyev

Ní December 16, 2020, Ilé Ẹjọ́ agbègbè Leninskiy tó wà ní ìlú Novosibirsk ní kí wọ́n fi Arákùnrin Yuriy Savelyev sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà. Àmọ́ ìyẹn ò bomi paná ìgbàgbọ́ Arákùnrin Yuriy wa ọ̀wọ́n. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mú kó túbọ̀ nígboyà.

Nígbà tí Arákùnrin Yuriy ń sọ̀rọ̀ ìparí nílé ẹjọ́ yẹn ní December 9, ó lo àǹfààní yẹn láti fìgboyà jẹ́rìí. Ó sọ fún gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ lọ́jọ́ náà pé: “Ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù Kristi sọ ló ń ṣẹ báyìí níṣojú yín. Ó wà nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn Bíbélì, nínú Máàkù 13:​9, níbi tó ti sọ pé: ‘Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín. Àwọn èèyàn máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́, wọ́n máa lù yín nínú àwọn sínágọ́gù, ẹ sì máa dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.’”