Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 6, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Dá Dennis Christensen Lẹ́bi, Wọ́n sì Rán An Lẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Dá Dennis Christensen Lẹ́bi, Wọ́n sì Rán An Lẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Ní February 6, 2019, ilé ẹjọ́ kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá Dennis Christensen lẹ́bi pé ó “ń ṣètò iṣẹ́ àjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà. Àwọn oníròyìn láwọn ilẹ̀ míì ti sọ̀rọ̀ nípa ẹjọ́ tí kò tọ́ yìí, a sì máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

A ò ní dákẹ́ àdúrà fún Dennis Christensen àti ìyàwó rẹ̀, Irina pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà bí wọ́n ṣe ‘fara balẹ̀, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé’ Jèhófà.—Àìsáyà 30:15.

 

Kà Sí I