Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 19, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Dẹ́bi fún Dennis Christensen Láìṣẹ̀ Láìrò, Wọ́n sì Rán An Lẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Dẹ́bi fún Dennis Christensen Láìṣẹ̀ Láìrò, Wọ́n sì Rán An Lẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà

Bá a ṣe sọ nínú ìròyìn tó jáde ní February 6, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Zheleznodorozhniy nílùú Oryol ti rán Arákùnrin Dennis Christensen lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà torí pé ó ń jọ́sìn pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin náà ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ gíga.

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló kọminú sí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún arákùnrin wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù, Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, Àjọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé, Ọ́fíìsì Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn àti onírúurú àwọn àjọ míì ló ti kéde pé ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe fún Christensen kò bẹ́tọ̀ọ́ mu rárá àti pé wọ́n kàn ń fìyà jẹ aláìṣẹ̀ ni.

Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ìyẹn Michelle Bachelet sọ pé: “Ẹjọ́ tí wọ́n dá fún Christensen lè dá wàhálà sílẹ̀ torí pé láti ìsinsìnyí lọ, ilé ẹjọ́ lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba sọ pé gbogbo èèyàn lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n.” Ó wá gba ìjọba Rọ́ṣíà níyànjú pé kí wọ́n “ṣàyẹ̀wò òfin tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn kí wọ́n lè ṣàtúnṣe sí ìtumọ̀ tí wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà ‘agbawèrèmẹ́sìn.’ Kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn alákatakítí tó ń hùwà jàgídíjàgan ni wọ́n kà sí agbawèrèmẹ́sìn.” Bachelet wá sọ ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn aláṣẹ “wọ́gi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn tó ń lo òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, àwọn tó lómìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́ àti láti pé jọ ní àlàáfíà, kí wọ́n sì dá àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀ lómìnira.”

Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí wọ́n dájọ́ Arákùnrin Christensen, àwọn gbajúgbajà mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà ṣètò ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn oníròyìn nílùú Moscow. Èrò kún fọ́fọ́ níbi tí wọ́n ti ṣèpàdé náà, àwọn tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ló ń wo ètò náà bí wọ́n ṣe ń ṣe é látorí íńtánẹ́ẹ̀tì. Gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà ló gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sọ pé èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, wọn kì í sì í dá wàhálà sílẹ̀ nílùú.

Ìpàdé àwọn oníròyìn nílùú Moscow ní February 8, 2019.

Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni ìyàwó Arákùnrin Christensen, ìyẹn Irina; agbẹjọ́rò rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Anton Bogdanov; àti aṣojú Àjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn Yaroslav Sivulskiy. Gbogbo wọn ló sọ̀rọ̀ nípa ẹjọ́ àìtọ́ tí wọ́n dá fún Arákùnrin Christensen, wọ́n sì dáhùn ìbéèrè àwọn oníròyìn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Christensen ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo ọdún méjì lẹ́wọ̀n, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ń láyọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn tó sọ nílé ẹjọ́ ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n dájọ́ rẹ̀, Arákùnrin Christensen sọ pé: “Bópẹ́ bóyá, ohun tó jẹ́ òótọ́ máa hàn kedere, bó sì ṣe máa rí nínú ẹjọ́ yìí náà nìyẹn.” Lẹ́yìn tó ka Ìfihàn 21:3-5, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí . . . sọ nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ òdodo, tá a sì fún gbogbo èèyàn ní òmìnira tòótọ́. Ìdájọ́ òdodo ló ń mú kéèyàn ní òmìnira tòótọ́. Ọlọ́run á sì rí i dájú pé gbogbo èèyàn rí ìdájọ́ òdodo gbà.”

Títí dìgbà tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, Arákùnrin Christensen ṣì máa wà ní àtìmọ́lé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní ìpínlẹ̀ Oryol, níbi tó ti wà láti nǹkan bí ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ.

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà wà pẹ̀lú Arákùnrin Dennis Christensen àti ìyàwó rẹ̀. Kó sì tún dúró ti gbogbo àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.—1 Pétérù 3:12.

Nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa dájọ́ arákùnrin náà, ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde kan, ìyẹn RFE/RL ṣe fídíò kan tí wọ́n pè ní Russian Trial Called ‘A Litmus Test For Religious Freedom’ (ìyẹn, Ìgbẹ́jọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Tó Máa Jẹ́ ‘Ìlànà Fáwọn Ẹjọ́ Míì Nípa Òmìnira Ẹ̀sìn’).