Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Yevgeniy Fedin àti Arákùnrin Sergey Loginov

MAY 2, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́síà Tú Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Kù Látìmọ́lé Sílẹ̀ ní Ìlú Surgut

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́síà Tú Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Kù Látìmọ́lé Sílẹ̀ ní Ìlú Surgut

Ní April 9, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Surgut pàṣẹ pé kí wọ́n tú Arákùnrin Yevgeniy Fedin àti Arákùnrin Sergey Loginov sílẹ̀ ní àtìmọ́lé. Ìpinnu yìí wọ́gi lé ohun táwọn aláṣẹ ní Rọ́ṣíà béèrè pé kí wọ́n fi kún àsìkò táwọn arákùnrin yìí máa lò látìmọ́lé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn arákùnrin méjèèjì, wọ́n fún wọn láyè láti kúrò látìmọ́lé ní April 11.

Ìgbà táwọn aláṣẹ tú ilé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nílùú Surgut ní February 15, 2019 ni wọ́n mú Arákùnrin Fedin àti Arákùnrin Loginov, tí wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé. Lásìkò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kàndínlógún (19) làwọn aláṣẹ fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn. Wọ́n sì ju mẹ́ta lára wọn sátìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn, àwọn ni: Yevgeniy àti Sergey pẹ̀lú Arákùnrin Artur Severinchik. Ní March 15, wọ́n tú Artur sílẹ̀.

Nígbà tí wọ́n ń kó àwọn èèyàn lóṣù February, àwọn agbofinró dá méje lára àwọn ará wa lóró, Arákùnrin Loginov sì wà lára àwọn tí wọ́n dá lóró náà. A fi ẹjọ́ bí wọ́n ṣe dá àwọn ará wa lóró yìí sùn ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Wọ́n sì ti ń gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà ó ní yé fi hàn pé òun ń fiyè sí gbogbo àdúrà wa, bó ṣe ń fún àwọn ará wa olóòótọ́ lókun ní Rọ́ṣíà.—Sáàmù 10:17.