Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó wà nílùú Strasbourg, nílẹ̀ Faransé

JUNE 10, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣì Ń Tàpá sí Òfin Àwọn Orílẹ̀-èdè Lẹ́yìn Ọdún Mẹ́wàá Tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Ẹjọ́ Mánigbàgbé

Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣì Ń Tàpá sí Òfin Àwọn Orílẹ̀-èdè Lẹ́yìn Ọdún Mẹ́wàá Tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Ẹjọ́ Mánigbàgbé

Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, ìyẹn ní June 10, 2010, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) sọ pé àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti tẹ òmìnira àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú gan-an, bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti ń wá ọ̀nà láti dí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n má lè jọ́sìn fàlàlà. Nínú ẹjọ́ tí wọ́n (ECHR) dá yìí, wọ́n ní kí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà san owó ìtanràn tó pọ̀, kí wọ́n sì tún fi orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Moscow sílẹ̀ lábẹ́ òfin lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kọ̀ jálẹ̀ lọ́dún 2004.

Gbàrà tí wọ́n kéde ìdájọ́ yìí, Arákùnrin Ivan Chaykovskiy tó jẹ́ alága àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Moscow nígbà yẹn sọ pé: “Ìdájọ́ tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ká rí bí ohun tó bọ́gbọ́n mu ṣe borí ẹ̀tanú ìsìn. Mo gbà pé ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí máa mú káwọn aláṣẹ tètè dá ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa dà, kí wọ́n sì fòpin sí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sí wọn káàkiri orílẹ̀-èdè yìí.”

Ohun tá a retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ kọ́ ló ṣẹlẹ̀. Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ náà sọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń koná mọ́ inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa níbi gbogbo lórílẹ̀-èdè náà. Inúnibíni náà wá peléke sí i nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de ẹ̀sìn wa lọ́dún 2017. Ẹjọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n dá yìí ló mú káwọn aláṣẹ máa fi àwọn ará wa sátìmọ́lé, kí wọ́n máa gbé wọn lọlé ẹjọ́, kí wọ́n sì máa jù wọ́n sẹ́wọ̀n.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ọdún mẹ́wàá báyìí tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti sọ ohun tó yẹ kí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fún wọn, púpọ̀ nínú ẹjọ́ tí wọ́n dá ló ṣì wúlò títí dòní. Lọ́dún 2010, ilé ẹjọ́ náà wọ́gi lé ọ̀pọ̀ nínú ẹjọ́ tí kò tọ́ táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń dá fáwọn ará wa.

Ibi tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù wá parí ọ̀rọ̀ sí ni pé, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹjọ́ ní Moscow àti àwọn ilé ẹjọ́ tó wà ní Moscow ò ní “ìdí kankan lábẹ́ òfin” láti sọ pé àwọn ò gbà láti forúkọ ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ohun táwọn aláṣẹ ìlú Moscow ṣe ò dáa tó, wọ́n ní “wọ́n ń gbè sápá kan, wọn ò sì dá ẹjọ́ lọ́nà tó tọ́.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláṣẹ ìlú Moscow jẹ̀bi, torí wọn ò tẹ̀ lé Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn máa ṣe.

Àwọn èèyàn ń rí gbogbo bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń ṣe inúnibíni sáwọn ará wa, bó ṣe rí lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn náà ló rí lónìí. Rachel Denber tó jẹ́ igbákejì adarí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn nílẹ̀ Yúróòpù àti àárín gbùngbùn Éṣíà, sọ pé: “Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá fẹ́ máa ṣe ẹ̀sìn wọn, òmìnira wọn ni wọ́n fi ń ṣeré yẹn.” Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní January 9, 2020, ó sọ pé: “Kò sí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi yẹ kí irú nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.”

A ò ní dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà á máa fún wọn lókun kí wọ́n lè “fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.”​—Kólósè 1:11.