Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Kaleriya Mamykina, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) tó ń jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ní Rọ́ṣíà torí ohun tó gbà gbọ́

JUNE 26, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Rọ́ṣíà Dájú Sọ Àwọn Àgbàlàgbà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Títí Kan Àwọn Tó Ti Lé ní Àádọ́rin Ọdún

Rọ́ṣíà Dájú Sọ Àwọn Àgbàlàgbà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Títí Kan Àwọn Tó Ti Lé ní Àádọ́rin Ọdún

Arákùnrin Boris Burylov, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ní ìlú Perm’

Ní May 2019, àwọn aláṣẹ agbègbè Arkhangel’sk àti Volgograd lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan arábìnrin wa méjì tó jẹ́ àgbàlagbà. Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí Arábìnrin Kaleriya Mamykina, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) tí àwòrán rẹ̀ wà lókè àti Arábìnrin Valentina Makhmadgaeva, ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin (71), wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n.

Ní April 2018, àwọn aláṣẹ ìlú Vladivostok fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arábìnrin Yelena Zayshchukbrought, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) pẹ̀lú àwọn mẹ́rin míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní báyìí mẹ́wàá nínú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún ló ń jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run láìda ẹnikẹ́ni láàmú lórílẹ̀-èdè Rọ́síà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan nínú wọn látìmọ́lé, kò rọrùn fún wọn rárá torí ara tó ti ń dara àgbà. Tí ìwádìí náà bá ṣì ń bá a lọ, tí ilé ẹjọ́ sì dá wọn lẹ́bi, wọ́n lè bu owó ìtánràn lù wọ́n tàbí kí wọ́n rán wọn lẹ́wọ̀n.

Títí di June 17, 2019, iye àwọn ará wa tí wọ́n ń jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn èké ìwà ọdaràn tí wọ́n fi kàn wọ́n jẹ́ igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (215). Ńṣe ni iye wọn sì ń pọ̀ sí i. Ẹ jẹ́ ká máa rántí gbogbo àwọn ará wa ní Rọ́síà nínú àdúrà wa, ká sì máa dárúkọ wọn ní pàtó. Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa mú kí ‘agbára rẹ̀ ológo fún wọn ní gbogbo agbára tí wọ́n nílò, kí wọ́n lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.’​—Kólósè 1:11.