Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Moskalenko ya fọ́tò níwájú ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n

SEPTEMBER 4, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Dá Arákùnrin Valeriy Moskalenko Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Wọ́n Dá Arákùnrin Valeriy Moskalenko Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Ní September 2, 2019, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Zheleznodorozhniy ní ìlú Khabarovsk lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dájọ́ pé kí Arákùnrin Valeriy Moskalenko lọ ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú fún ọdún méjì àti oṣù méjì. Ẹ̀yìn ìyẹn ní wọ́n á wá máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ fún oṣù mẹ́fà. Ìyẹn túmọ̀ sí pé kò ní pa dà sẹ́wọ̀n mọ́.

Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ kéde ìdájọ́ yìí, wọ́n dá Arákùnrin Moskalenko sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, inú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì dùn gan-an. Láti August 2, 2018 ló ti wà lẹ́wọ̀n. Kí wọ́n tó fi í sẹ́wọ̀n, iṣẹ́ tó ń ṣe ni pé ó máa ń ran ẹni tó ń wa ọkọ̀ ojú irin lọ́wọ́, ó sì tún ń tọ́jú ìyá rẹ̀ tó ń ṣàìsàn. Lára àwọn ìkálọ́wọ́kò tí wọ́n fún un lásìkò tí wọ́n fi ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ ni pé kò gbọdọ̀ jáde kúrò nílùú Khabarovsk, ó sì gbọ́dọ̀ máa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lóṣooṣù kí wọ́n lè rí i pé kò ṣe ohunkóhun tí kò bófin mu.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Moskalenko sọ kẹ́yìn nílé ẹjọ́ ní August 30, ó sọ pé: “Mi ò ni ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì láé. Bó ti wù kí ilé ẹjọ́ yìí fìyà jẹ mí tó, kódà tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún mi, mi ò ni fi Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè àti Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run sílẹ̀ láé.”

Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ aṣojú Àjọ European Association of Jehovah’s Witnesses, sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò gbà pé a jẹ̀bi ẹ̀sùn náà, àmọ́ inú wa dùn pé Valeriy máa lè pa dà sílé.”

Yàtọ̀ sí Arákùnrin Moskalenko, àwọn arákùnrin wa méje míì wà ní ìlú Khabarovsk tó ń retí ìgbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé Arákùnrin Moskalenkodúró gbọin nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà túbọ̀ máa fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lókun bí wọ́n ṣe ń fara da inúnibíni nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.​—Àìsáyà 40:31.