Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Andrey Stupnikov (láàárín), pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dá a sílẹ̀ látìmọ́lé

JULY 5, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Dá Arakùnrin Stupnikov Sílẹ̀ Látìmọ́lé

Wọ́n Dá Arakùnrin Stupnikov Sílẹ̀ Látìmọ́lé

Ní July 2, 2019, ilé ẹjọ́ kan ní ìlú Krasnoyarsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dájọ́ pé kí wọ́n fi Arákùnrin Andrey Stupnikov sílẹ̀, kí wọ́n má ṣe sé e mọ́lé mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sé e mọ́lé mọ́, àwọn aláṣẹ ṣì kà á sí ọ̀daràn, wọ́n sì ń bá ìwádìí lọ lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Arákùnrin Andrey Stupnikov

Ní July 3, 2018, bí ìdílé Stupnikov ṣe fẹ́ wọkọ̀ òfúrufú láàárọ̀ kùtù ní Pápákọ̀ Òfúrufú Krasnoyarsk, ní Yemelyanovo, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbọ̀ ìjọba méjì fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Stupnikov. Odindi oṣù mẹ́jọ ló lò ní ẹ̀wọ̀n láìjẹ́ pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ rárá, lẹ́yìn náà ni wọ́n sé e mọ́lé láti ìparí oṣù February, 2019.

Bí arákùnrin Stupnikov ṣe sọ, ohun tójú ẹ̀ rí láàárín ọdún kan yìí ti jẹ́ kó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ara ẹ̀ àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ó sọ pé: “[Èmi àti Olga] ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àmọ́ a ò sún mọ́ Jèhófà tó báyìí rí láyé wa! Láwọn ìgbà tí nǹkan nira gan-an, mo máa ń rí bí Bàbá wa ọ̀run ṣe ń tù mí nínú tó sì ń ràn mí lọ́wọ́. Ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí bí Jèhófà ṣe ń dúró tì mí tó sì máa ń tètè dáhùn àdúrà mi!”

Arákùnrin Stupnikov parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó ti wá dá mi lójú pé Jèhófà Bàbá mi lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára mi torí pé ó mọ̀ mí dáadáa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí ti jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n gbára lé Jèhófà pátápátá, kí n má sì máa da ara mi láàmú ju bó ṣe yẹ lọ nítorí inúnibíni. Mo tún rí i pé èèyàn máa kábàámọ̀ tó bá pàdánù irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ó dá mi lójú pé tí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, kò síṣòro tá ò ní lè borí.”

Láti July 1, ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ti fi kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti tó igba ó lé mẹ́tàdínlógún (217). Láwọn ipò kan, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti dín ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ara wa kan kù. Àmọ́, kì í ṣe àwọn aláṣẹ ilé ẹjọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé, Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa fún àwọn ará wa tó wà ní Rọ́ṣíà lágbára, kó sì máa dáàbò bò wọ́n.​—⁠Sáàmù 28:7.