JUNE 9, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Wọ́n Dájọ́ Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà Àtààbọ̀ fún Arákùnrin Gennady Shpakovskiy Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà
Lọ́jọ́ Tuesday, June 9, 2020, ilé ẹjọ́ Pskov City Court dẹ́bi fún Arákùnrin Gennady Shpakovskiy tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61), wọ́n sì dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà àtààbọ̀ fún un. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n dájọ́ fún un tán ni wọ́n mú un lọ sínú ẹ̀wọ̀n. Iye ọdún tí wọ́n dá fún arákùnrin wa yìí ló ṣì pọ̀ jù láti ọdún 2017 tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti ṣòfin pé ọ̀daràn ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tó ń ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Shpakovskiy máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un.