Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 12, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Fẹ̀sùn Ìwà Ọ̀daràn Kan Arákùnrin Yevgeniy Aksenov Torí Pé Ó Sọ̀rọ̀ Nípa Bíbélì

Wọ́n Fẹ̀sùn Ìwà Ọ̀daràn Kan Arákùnrin Yevgeniy Aksenov Torí Pé Ó Sọ̀rọ̀ Nípa Bíbélì

Ilé ẹjọ́ agbègbè Zheleznodorozhniy tó wà nílùú Khabarovsk máa dá ẹjọ́ Arákùnrin Yevgeniy Aksenov ní Friday, February 14, 2020, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Agbẹjọ́rò ìjọba fẹ́ kí wọ́n fi arákùnrin náà sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta.

Ní April 21, 2018, Arákùnrin Aksenov péjọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ní yàrá àpérò ní hòtẹ́ẹ̀lì kan láti sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Níbi ìjíròrò yẹn, ó bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. Fún ìdí yẹn, wọ́n fẹ̀sùn “ìwà ọ̀daràn tó burú jáì” kàn án, wọ́n sì pè é lẹ́jọ́ fún “ṣíṣètò ìgbòkègbodò àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní October 21, 2019.

Bí ìgbẹ́jọ́ Arákùnrin Aksenov ṣe ń parí lọ, àdúrà wa ni pé kí òun àti ìdílé ẹ̀ túbọ̀ gbára lé Jèhófà, kí wọ́n sì fọkàn sí ìlérí rẹ̀ pé àwọn ẹni ìdúróṣinṣin “kò ní ṣaláìní” ohunkóhun.​—Sáàmù 34:9.