NOVEMBER 25, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Wọ́n Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Ọ̀dọ́kùnrin Semyon Baybak Nítorí Ohun Tó Gbà Gbọ́
Ìdájọ́
Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Leninskiy tó wà ní Rostov-on-Don ti pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Semyon Baybak ní December 18, 2020. * Ohun táwọn alátakò fẹ́ ni pé kílé ẹjọ́ ní kí Arákùnrin Semyon lo ọdún mẹ́rin tó yẹ kó lò lẹ́wọ̀n nílé, káwọn agbófinró sì máa ṣọ́ ọ.
Ìsọfúnni Ṣókí
Semyon Baybak
Wọ́n Bí I Ní: 1997 (nílùú Rostov-on-Don)
Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan àti ẹ̀gbọ́n obìnrin kan. Ó kọ́ èdè Chinese, ó sì ń kọ́ àwọn èèyàn lédè náà. Ó fẹ́ràn kó máa kàwé, kó sì máa kọ ewì
Àtikékeré làwọn òbí ẹ̀ ti ń kọ́ ọ nípa Jèhófà. Bó sì ṣe ń dàgbà ló ń mọyì àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́. Torí àwọn nǹkan tó ti kọ́ látinú Bíbélì, ó pinnu pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun. Torí náà, láàárín ọdún 2015 sí 2017 wọ́n ní kó ṣiṣẹ́ àṣesìnlú míì, wọ́n ní kó máa gbá ọgbà ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn ọmọdé
Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí I Tẹ́lẹ̀
Ní May 22, 2019, àwọn agbófinró láti àjọ ilé iṣẹ́ tó ń gbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàlá nílùú Rostov-on-Don. Ní June 6, 2019, ìyẹn ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Semyon. Nígbà tó yá, wọ́n fi í sátìmọ́lé, lẹ́yìn náà ilé ẹjọ́ ní kó pa dà sílé, wọ́n sì ní káwọn agbófinró máa ṣọ́ ọ. Wọ́n kọ́kọ́ ní kó lo ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ nílé, nígbà tí ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ yẹn pé, wọ́n tún ní kó lo ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ míì. Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílé ẹjọ́ sì fi sún un síwájú bẹ́ẹ̀.
Àwọn agbófinró kọ́kọ́ fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Semyon torí pé ó ń lọ sípàdé tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ ohun tó ń kọ́ látinú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ní November 2019, wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án pé ó ń fowó ṣètìlẹyìn fáwọn tí ìjọba kà sí agbawèrèmẹ́sìn.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ túbọ̀ ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó dá wa lójú pé Jèhófà “Ọlọ́run àlàáfíà” á máa bá a lọ láti fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò, kí wọ́n lè máa “ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”—Hébérù 13:20, 21.
^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà.