Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 11, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Fẹ̀sùn Kan Arákùnrin Mikhail Popov àti Ìyàwó Rẹ̀, Yelena Ní Rọ́ṣíà—À Ń Retí Ohun Tí Ilé Ẹjọ́ Máa Sọ Ní February 13, 2020

Wọ́n Fẹ̀sùn Kan Arákùnrin Mikhail Popov àti Ìyàwó Rẹ̀, Yelena Ní Rọ́ṣíà—À Ń Retí Ohun Tí Ilé Ẹjọ́ Máa Sọ Ní February 13, 2020

A retí pé kí ilé ẹjọ́ Vilyuchinsk City Court sọ ìdájọ́ wọn lórí ọ̀rọ̀ Arákùnrin Mikhail Popov àti ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popova lọ́jọ́ Thursday, February 13, 2020. Wọ́n mú tọkọtaya yìí ní July 30, 2018 ní ìlú Kamchatka, àmọ́ wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ ní August 9, 2018. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ni pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí “iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.”

Mikhail àti Yelena gbára lé Jèhófà pátápátá bí wọ́n ṣe ń fara da ipò tó le koko yìí. Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa bá a lọ láti jẹ́ ‘ibi ààbò àti okun’fún wọn.—Sáàmù 46:1.