SEPTEMBER 3, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Wọ́n Fi Àwọn Arákùnrin Méjì àti Arábìnrin Méjì Sẹ́wọ̀n Nítorí Ìgbàgbọ́ Wọn
Ìdájọ́
Ní September 3, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Novozybkov tó wà lágbègbè Bryansk ní kí wọ́n fi Arákùnrin Vladimir Khokhlov, Arábìnrin Tatyana Shamsheva, Arábìnrin Olga Silaeva, àti Arákùnrin Eduard Zhinzhikov sẹ́wọ̀n. Wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan lo ọdún kan tàbí ọdún kan àti oṣù mẹ́ta lẹ́wọ̀n. Àmọ́, torí pé wọ́n ti lo iye àkókò yẹn látìmọ́lé, wọ́n dá wọn sílẹ̀.
Ìsọfúnni Ṣókí
Vladimir Khokhlov
Wọ́n Bí I Ní: 1977 (ní ìlú Novozybkov, lágbègbè Bryansk)
Ìtàn Ìgbésí Ayé: Iṣẹ́ mẹkáníìkì ló ń ṣe. Ó ti ṣe iṣẹ́ ológun kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fẹ́ràn láti máa gbá bọ́ọ̀lù, láti máa kàwé, láti máa pẹja àti láti máa ta gìtá
Ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan ló gbà á nímọ̀ràn pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó fẹ́ Olga lọ́dún 2007. Anastasia lorúkọ ọmọbìnrin wọn. Ní báyìí, gbogbo wọn ló ń sin Jèhófà
Tatyana Shamsheva
Wọ́n Bí I Ní: 1977 (ní ìlú Cherepovets, lágbègbè Vologda)
Ìtàn Ìgbésí Ayé: Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ni. Ó ṣe iṣẹ́ olùkọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó kọ́ àwọn èèyàn ní ètò ọrọ̀ ajé, ìmọ̀ òfin àti ìṣirò. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1995. Ó fẹ́ràn láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì
Olga Silaeva
Wọ́n Bí I Ní: 1988 (ní Davydovo, lágbègbè Moscow)
Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ọmọ mẹ́ta làwọn òbí ẹ̀ bí, òun sì ni àbíkẹ́yìn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ níléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́, ó sì gboyè jáde. Ó fẹ́ràn láti máa ránṣọ, láti máa kàwé àti láti máa gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá. Màmá ẹ̀ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó yá òun náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Eduard Zhinzhikov
Wọ́n Bí I Ní: 1971 (ní Zadnya, lágbègbè Bryansk)
Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó ti ṣe iṣẹ́ jórinjórin, aṣọ́gbà àti iṣẹ́ ọlọ́pàá rí. Inú ẹgbẹ́ akọrin kan ló wà tẹ́lẹ̀, inú ẹgbẹ́ yìí ló sì ti rí obìnrin kan tó ń jẹ́ Tatyana tó fẹ́ lọ́dún 1993. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti láti máa ta gìtá
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣáájú ọdún 2000, ó sì rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ìyẹn wá mú kó yí àwọn ìwà burúkú tó ń hù tẹ́lẹ̀ pa dà, ìdílé rẹ̀ sì ń láyọ̀. Àwọn àyípadà tó ṣe yìí wú Tatyana lórí. Nígbà tó yá òun náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Wọn Tẹ́lẹ̀
Ní June 11, 2019, àwọn agbófinró ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìlélógún (22) lágbègbè Bryansk ní Rọ́ṣíà. Wọ́n mú Arábìnrin Tatyana Shamsheva àti Arábìnrin Olga Silaeva. Wọ́n kọ́kọ́ fi wọ́n sátìmọ́lé fún igba ó lé márùnlélógójì ọjọ́ (245). Ní May 2020, wọ́n tú wọn sílẹ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n máa retí ọjọ́ tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ wọn.
Ní October 16, 2019, àwọn agbófinró fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Vladimir Khokhlov àti Arákùnrin Eduard Zhinzhikov. Nígbà tó yá, wọ́n da ẹjọ́ àwọn arákùnrin yìí papọ̀ mọ́ ti Arábìnrin Shamsheva àti Arábìnrin Silaeva. Ní ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, wọ́n fi àwọn arákùnrin yẹn sátìmọ́lé, ibẹ̀ ni wọ́n sì wà títí di báyìí.
Nínú fídíò Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2020 #5, a gbọ́rọ̀ látẹnu Arábìnrin Shamsheva àti Arábìnrin Silaeva. Arábìnrin Silaeva sọ pé oṣù mẹ́jọ tóun lò látìmọ́lé jẹ́ kó túbọ̀ dá òun lójú pé “kò sí bíṣòro yẹn ṣe lè le tó, Jèhófà máa fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀ bá a ṣe nílò rẹ̀ tó ká lè kojú ìṣòro tá a ní.” Bákan náà, Arábìnrin Shamsheva fi ìdánilójú sọ pé: “Jèhófà máa ń dúró tì wá, ó máa ń gbé wa ró, ó máa ń dì wá mú, ó sì máa ń fún wa lókun.”
Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró ti àwọn ará wa tí wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n àtàwọn míì tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn lọ́wọ́ ní Rọ́ṣíà, á fún wọn lókun kí wọ́n lè máa láyọ̀, kí ọkàn wọn sì balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fara dà á.—1 Kọ́ríńtì 10:13.