Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 24, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Fi Arákùnrin Dennis Christensen Sínú Yàrá Tí Wọ́n Ti Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lẹ́ẹ̀kejì

Wọ́n Fi Arákùnrin Dennis Christensen Sínú Yàrá Tí Wọ́n Ti Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lẹ́ẹ̀kejì

Ní July 15, 2020, wọ́n fi Arákùnrin  Dennis Christensen sínú yàrá tí wọ́n máa ń fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó rú òfin pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n sí, (ìyẹn SHIZO), ìgbà kejì sì rèé tí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Arakùnrin wa yìí máa wà níbẹ̀ títí di ó kéré tán, July 27. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹrin tí wọ́n mú un kúrò ní yàrá àwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí ni wọ́n tún dá a pa dà síbẹ̀. Tí wọ́n bá dá arákùnrin wa pa dà sínú yàrá yìí nígbà kẹta, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé “ẹni tó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin inú ọgbà ẹ̀wọ̀n” ni, ìyẹn sì lè jẹ́ kí wọ́n mú un lọ sínú yàrá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó burú ju ti àkọ́kọ́ lọ, ìyẹn yàrá tí wọ́n máa ń fi àwọn ọ̀daràn paraku sí (EPKT), kó sì lo ohun tó tó oṣù mẹ́fà níbẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò Arákùnrin Christensen máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí.

Àwọn aláṣẹ ń fìyà jẹ Arákùnrin Christensen torí pé ìlera ẹ̀ ò jẹ́ kó ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fún un lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ pé kí Arákùnrin  Christensen máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń ran aṣọ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Àmọ́ látìgbà tó ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìlera tó dáa. Àwọn dókítà ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ pé Arákùnrin Christensen ní ìlera tó dáa láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó máa ṣe, àmọ́ ṣe ló kàn nílò àtimáa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí dókítà míì tí kò sí lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ṣàyẹ̀wò Arákùnrin Christensen, ohun tó sọ ni pé ìlera Arákùnrin Christensen ò ní lè jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó ṣe.

Nínú yàrá tí wọ́n máa ń fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó rú òfin pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n sí, wọn kì í gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n láyè láti ra oúnjẹ, wọn ò lè pè, wọn ò sì lè gba ìpè lórí fóònù. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í jẹ́ káwọn èèyàn wọn wá rí wọn tàbí kí wọ́n gbé nǹkan wá fún wọn. Àmọ́ wọ́n máa ń gbà káwọn aṣáájú ẹ̀sìn wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Ní ti Arákùnrin Christensen, àwọn alàgbà ò láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ̀, torí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ṣáájú àkókó yẹn, ní June 23 ilé ẹjọ́ Lgov sọ pé kí wọ́n dá Arákùnrin Christensen sílẹ̀ àti pé kó san owó ìtanràn, kí wọ́n lè fagi lé àkókò tó kù tó máa lò lẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, àwọn tó pè é lẹ́jọ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ó jọ pé ṣe ni wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n lè ba Arákùnrin Christensen lórúkọ jẹ́, kí wọ́n má sì tètè dá a sílẹ̀.

Síbẹ̀, Arákùnrin Christensen àti Irina ìyàwó ẹ̀ ò banú jẹ́. Ṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára sí i bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fara da àwọn àtakò tó le gan-an.​—Kólósè 1:11.