Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 2, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Fi Arákùnrin Sergey Britvin àti Arákùnrin Vadim Levchuk Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́rin ní Rọ́ṣíà

Wọ́n Fi Arákùnrin Sergey Britvin àti Arákùnrin Vadim Levchuk Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́rin ní Rọ́ṣíà

Ní September 2, 2020, Ilé Ẹjọ́ Berezovsky tó wà lágbègbè Kemerovo fi Arákùnrin Sergey Britvin àti Arákùnrin Vadim Levchuk sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin. Àmọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà àtààbọ̀ làwọn alátakò fẹ́ kí wọ́n fi wọ́n sí. Àwọn arákùnrin wa yìí máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.