Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 31, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Máa Dá Ẹjọ́ Dennis Christensen ní February 6, 2019

Wọ́n Máa Dá Ẹjọ́ Dennis Christensen ní February 6, 2019

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Zheleznodorozhniy tó wà ní ìlú Oryol ti parí gbígbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen, adájọ́ sì máa sọ ìdájọ́ rẹ̀ ní Wednesday, February 6, 2019.

Àtìgbà tí wọ́n ti mú Arákùnrin Christensen ní May 25, 2017 ló ti wà látìmọ́lé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án ní February 19, 2018. Tí ilé ẹjọ́ bá dá Arákùnrin Christensen lẹ́bi, àwọn tó fẹ̀sùn kàn án ti sọ pé kí wọ́n rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà àtààbọ̀.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ogún (20) oṣù tí Arákùnrin Christensen ti wà lẹ́wọ̀n, kò bọkàn jẹ́, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ó sì mọyì àdúrà táwọn ará kárí ayé ń gbà fún òun.—2 Tẹsalóníkà 3:1, 2.