Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 30, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Ní Kí Wọ́n Dá Arákùnrin Dennis Christensen Sílẹ̀

Wọ́n Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Ní Kí Wọ́n Dá Arákùnrin Dennis Christensen Sílẹ̀

A gbọ́ pé ọ̀gbẹ́ni A. A. Shatunov tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Olùpẹ̀jọ́ tó wà lágbègbè Kursk ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe ní kí wọ́n tètè dá Arákùnrin Dennis Christensen sílẹ̀. Lóòótọ́ àwọn agbẹjọ́rò Arákùnrin Christensen máa gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ ó máa tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí ilé ẹjọ́ tó lè gbọ́ ẹjọ́ náà. Wọ́n ti fi Arákùnrin Christensen sínú yàrá tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, ọjọ́ mẹ́wàá ló sì ti lò níbẹ̀. Láìka gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí sí, Arákùnrin Christensen ṣì ń láyọ̀. Ẹ ṣeun gan-an pé ẹ ò dákẹ́ àdúrà lórí Arákùnrin àti Arábìnrin Christensen.