Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Gennady Shpakovskiy rèé, pẹ̀lú Tatiana ìyàwó ẹ̀ àti Maria ọmọ ẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n

AUGUST 3, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Ti Dá Arákùnrin Gennady Shpakovskiy Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Wọ́n Ti Dá Arákùnrin Gennady Shpakovskiy Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Ní Monday, August 3, 2020, Ilé Ẹjọ́ Pskov sọ pé kí wọ́n dá Arákùnrin Gennady Shpakovskiy sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ ṣì gbà pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n ní kó máa lọ sílé dípò kó ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà ààbọ̀, àmọ́ àwọn aláṣẹ á ṣì máa ṣọ́ ọ títí ọdún mẹ́fà ààbọ̀ yẹn á fi pé, kódà ní ọdún méjì àkọ́kọ́, ilé ẹjọ́ náà á ṣì máa wò ó bóyá kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Kò ju wákàtí mélòó kan tí ilé ẹjọ́ dájọ́ yẹn tí wọ́n fi dá Arákùnrin Shpakovskiy sílẹ̀. Àwọn tó pè é lẹ́jọ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.