Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Tatyana Alushkina dì mọ́ Vladimir ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n

APRIL 10, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Ti Dá Arákùnrin Vladimir Alushkin Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Wọ́n Ti Dá Arákùnrin Vladimir Alushkin Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

A láyọ̀ láti sọ fún yín pé wọ́n ti dá Arákùnrin Vladimir Alushkin sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní March 30, 2020, inú òun àti ìyàwó ẹ̀ sì dùn gan-an pé àwọn tún jọ wà pa pọ̀.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, a gbé ìròyìn kan jáde ní March 25 nípa bí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Penza ṣe fagi lé ìpinnu tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe, tí wọ́n sì ní kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbọ́. Ìpinnu ilé ẹjọ́ kejì jẹ́ kó ṣe kedere pé Arákùnrin Vladimir Alushkin, Vladimir Kulyasov, Andrey Magliv àti Arákùnrin Denis Timoshin kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, bákan náà lọ̀rọ̀ sì rí pẹ̀lú Arábìnrin Tatyana Alushkina àti Galiya Olkhova. Nípa bẹ́ẹ̀, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Penza ní kí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ yan adájọ́ míì láti tún ẹjọ́ náà gbọ́. Kó tó di pé wọ́n tún ẹjọ́ yẹn gbọ́, wọ́n fòfin de àwọn ará wa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ rìnrìn-àjò, wọ́n sì tún fi àwọn ẹ̀tọ́ míì dù wọ́n.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn gan-an pé wọ́n ti dá Arákùnrin Alushkin sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó ká wa lára pé lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n tún mú ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa lápá àríwá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nítorí ohun tó gbà gbọ́. Títí dìgbà táwọn èèyàn fi máa ṣíwọ́ àtimáa fẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kan àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó dá wa lójú pé àwọn ará wa yìí á máa fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Náhúmù 1:7 sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere, odi agbára ní ọjọ́ wàhálà. Ó sì mọ àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.”