Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 11, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Ti Mú Arákùnrin Dennis Christensen Kúrò Níbi Tí Wọ́n Ti Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n

Wọ́n Ti Mú Arákùnrin Dennis Christensen Kúrò Níbi Tí Wọ́n Ti Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n

Ní July 11, 2020, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Lgov mú Arákùnrin Dennis Christensen pa dà síbi táwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù wà. Wọ́n mú un kúrò níbi tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, lẹ́yìn tó ti lo odindi ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún níbẹ̀. Bá a ṣe sọ nínú ìròyìn tó ṣáájú, torí ẹ̀sùn èké míì tí wọ́n fi kan Arákùnrin Christensen ni wọ́n ṣe lọ fìyà jẹ ẹ́. Síbẹ̀, kò bọ́hùn. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti mú un pa dà síbi táwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù wà. Àwọn agbẹjọ́rò Arákùnrin Christensen máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi kàn án yìí, kó má bàa ṣèdíwọ́ fún ẹjọ́ tí wọ́n ṣe ṣáájú pé kí wọ́n tú u sílẹ̀.