NOVEMBER 23, 2018
RỌ́ṢÍÀ
Wọ́n Ṣì Ń Kó Ọ̀pọ̀ Àwọn Ará Wa, Wọ́n sì Ń Fi Wọ́n sí Àtìmọ́lé ní Rọ́ṣíà
Nínú oṣù October 2018, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé tó ju ọgbọ̀n (30) lọ káàkiri ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Wọ́n mú arákùnrin mẹ́fà àti arábìnrin méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí ilé ẹjọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ wọn lórí ẹ̀sùn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Ní báyìí, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n ti rán lọ sẹ́wọ̀n láìtọ́ jẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), wọ́n sì sọ fún àwọn méjìdínlógún (18) míì pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé.
October 7, ní Sychyovka, Àgbègbè Smolensk—Àwọn ọlọ́pàá àdúgbò àtàwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú lọ tú ilé mẹ́rin, wọ́n sì mú arábìnrin méjì, ìyẹn Nataliya Sorokina tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì (43) àti Mariya Troshina tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41). Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n mú wọn, Ilé Ẹjọ́ Leninsky rán àwọn arábìnrin wa lọ sí àtìmọ́lé títí di November 19, 2018. Àmọ́ nígbà tó di November 16, 2018, Ilé Ẹjọ́ Leninsky fi oṣù mẹ́ta kún ọjọ́ táwọn arábìnrin wa máa lò látìmọ́lé, tó fi hàn pé wọ́n á wà níbẹ̀ títí di February 19, 2019 nìyẹn.
October 9, ní Kirov, Àgbègbè Kirov—Ó kéré tán, ilé mọ́kàndínlógún (19) ni wọ́n ya wọ̀. Wọ́n mú àwọn alàgbà ìjọ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ni mẹ́rin lára wọn (ìyẹn Maksim Khalturin, Vladimir Korobeynikov, Andrey Suvorkov àti Evgeniy Suvorkov) ẹnì kan tó kù, ìyẹn Andrzej Oniszczuk, jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland. Yàtọ̀ sí Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark, Arákùnrin Oniszczuk ló máa jẹ́ ẹnì kejì tó wá láti orílẹ̀-èdè míì táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà máa mú sílẹ̀ ní Rọ́ṣíà torí ohun tó gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.
October 18, ní Dyurtyuli, Republic of Bashkortostan—Ó kéré tán, ilé mọ́kànlá (11) làwọn ọlọ́pàá ya wọ̀, wọ́n sì gba owó, káàdì tí wọ́n fi ń gbowó ní báǹkì, fọ́tò, àwọn lẹ́tà àdáni, kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká àti síìmù. Wọ́n mú Anton Lemeshev tó jẹ́ alàgbà, wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé fún oṣù méjì kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Nígbà tó di October 31, 2018, wọ́n dá a sílẹ̀ kó máa lọ sílé, àmọ́ wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, títí di bá a ṣe ń sọ yìí.
Láìka báwọn agbófinró ṣe ń ya wọ ilé àwọn ará, tí wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní wọn lọ́nà tí kò bófin mu, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin láwọn àgbègbè yìí ń ṣèrànwọ́ tí wọ́n lè ṣe fáwọn tó wà látìmọ́lé àti ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbàdúrà fún wọn. Títí tí ọ̀rọ̀ yìí fi máa yanjú, ẹgbẹ́ ará kárí ayé ò ní yéé bẹ Jèhófà torí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó wà ní Rọ́ṣíà, kódà, àá máa dárúkọ àwọn kan nínú àdúrà wa.—Éfésù 6:18.