Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Gbọ̀ngàn Àpéjọ Kolomyazhskiy ní St. Petersburg

DECEMBER 25, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aláṣẹ Gbẹ́sẹ̀ Lé Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Rọ́ṣíà

Àwọn Aláṣẹ Gbẹ́sẹ̀ Lé Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Rọ́ṣíà

Ní December 14, 2017 àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà já wọnú Gbọ̀ngàn Àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kolomyazhskiy, St. Petersburg, àwọn ọlọ́pàá yí Gbọ̀ngàn náà ká, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé e. Wọn ò ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ léṣe, ó sì jọ pé wọn ò ba ilé náà jẹ́.

Fọ́tò àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ya wọnú Gbọ̀ngàn náà

Látìgbà tí ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní Rọ́ṣíà ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní July 17, 2017, Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí ni ilé tó tóbi jù lọ tí ìjọba Rọ́ṣíà ti gbẹ́sẹ̀ lé. Ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ sọ pé kí ìjọba fòfin de gbogbo àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n gba gbogbo ẹ̀tọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lábẹ́ òfin láti ṣe ẹ̀sìn wa, ó sì tún ní kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo dúkìá tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lórílẹ̀-èdè náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wà nínú Gbọ̀ngàn náà

Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí ní ìjókòó tó lè gba èèyàn ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500]. Látìgbà tá a ti tún un kọ́ lọ́dún 2002 ni àwọn ìjọ tó wà ládùúgbò ti ń lò ó, a sì tún máa ń ṣe àwọn àpéjọ ńlá níbẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ìjọba Rọ́ṣíà ti sọ Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà di tiwọn. Ní báyìí wọ́n ti ní kí àwọn míì máa lo Gbọ̀ngàn náà, àwọn ilé ìwòsàn àdúgbò kan ló ń lo ibẹ̀ báyìí, wọ́n sì ti gbé àkọlé míì sára géètì gbọ̀ngàn náà.

Kò ju ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ sọ pé àwọn máa gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí St. Petersburg, tí àwọn nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀. Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ yìí ló wọ́gi lé àdéhùn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] tó wà láàárín ìjọba Rọ́ṣíà àti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Tó bá jẹ́ pé bákan náà lọ̀rọ̀ rí lẹ́yìn tá a bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ìyẹn ni pé ìjọba Rọ́ṣíà lè gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa papọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé míì tá a ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ tó ni àwọn ilé yìí kò sí lábẹ́ ìjọba Rọ́ṣíà.

Ó ṣe kedere sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ṣe ni ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kàn ń ṣe inúnibíni si wa ni, wọn ò sì jẹ́ ká lómìnira láti ṣe ìsìn wa, wọn tún wá ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé táà ń lò fún ìjọsìn wa, àwọn ilé tó jẹ́ pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ló rà á tí wọ́n sì tún un kọ́. A ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ń ṣe yìí, kódà a máa kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù àti Ìgbìmọ̀ To Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.