Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 26, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Títí Kan Ọmọ Ilẹ̀ Denmark Tó Wà Lẹ́wọ̀n, Pé Wọ́n Ran Ìlú Lọ́wọ́

Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Títí Kan Ọmọ Ilẹ̀ Denmark Tó Wà Lẹ́wọ̀n, Pé Wọ́n Ran Ìlú Lọ́wọ́

Ìwé táwọn aláṣẹ ìlú Oryol kọ nìyí: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ohun rere tẹ́ ẹ ṣe fún ìlú àti bẹ́ ẹ ṣe tún àyíká ṣe.”

NEW YORK—Ní June 2, 2017, àwọn aláṣẹ ìlú Oryol lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbóríyìn fún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú náà, wọ́n ní àwọn mọrírì bí wọ́n ṣe kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọba ṣe láti tún ìlú ṣe ní April 22, 2017. Àádọ́rin [70] làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara wọn lọ́jọ́ yẹn, tí wọ́n ń kó ìdọ̀tí tó wà láwọn ojú ọ̀nà ìlú Oryol àtàwọn ìdọ̀tí tó wà níbi odò Orlik River tó ṣàn káàkiri ìlú náà. Kí àwọn aláṣẹ ìlú náà lè fi hàn pé àwọn mọrírì iṣẹ́ yìí, wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀bùn kékeré kan, wọ́n sì kọ̀wé kékeré kan sí i. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ ni pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ohun rere tẹ́ ẹ ṣe fún ìlú àti bẹ́ ẹ ṣe tún àyíká ṣe.”

Àmọ́ lẹ́yìn oṣù kan tí wọ́n ṣiṣẹ́ àtúnṣe yìí, tó bọ́ sí ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú ìgbà tí àwọn aláṣẹ ìlú dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, àwọn agbófinró lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ní May 25, wọ́n sì mú ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nígbà àtúnṣe yẹn. Dennis Christensen lorúkọ ẹ̀, (àwòrán ẹ̀ ló dá wà lókè lápá ọ̀tún) wọ́n ní ó ń ṣiṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn làwọn ṣe mú un. Àwọn aláṣẹ ti máa ń fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Dennis Christensen ń ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n ń tún ìlú ṣe ní October 2011.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn sọ pé, “Kò ní ya àwọn tó bá mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu pé Dennis àtàwọn míì tó wà nínú ìjọ máa yọ̀ǹda ara wọn láti tún ìlú ṣe. Kì í ṣòní kì í ṣàná ni wọ́n ti ń ṣe irú iṣẹ́ yìí, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe é, kódà wọn ò dáwọ́ dúró látọdún 2016 tí ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Aráàlú rere làwọn èèyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Oryol sí, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láwọn ìlú míì kárí ayé. Ìdí nìyẹn tó fi rí bákan pé àwọn aláṣẹ máa mú Dennis ní ọ̀daràn, ẹni tó jẹ́ pé òṣìṣẹ́ kára ni, Kristẹni tó sì máa ń pa òfin ìlú mọ́ ni. Ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ sí ohun tó ṣe ìlú láǹfààní ni, táwọn aláṣẹ ìlú Oryol náà sì mọrírì ẹ̀. Ṣe la retí pé kí wọ́n tú Dennis sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, kí òun àti àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiẹ̀ lè jọ máa ṣe ìjọsìn wọn lọ ní àlàáfíà, kó sì lè máa ran ìlú lọ́wọ́ bó ṣe máa ń ṣe.”

Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Oryol ní June 14, 2016 làwọn aláṣẹ mú Ọ̀gbẹ́ni Christensen. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Rọ́ṣíà dájọ́ ní April 20, 2017, pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà tó wà nítòsí ìlú St. Petersburg, tí àwọn aláṣẹ fi fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Christensen. Ó ṣì wà ní àtìmọ́lé tí àwọn aláṣẹ ìlú Oryol fi sí di ìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000