Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 23, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aláṣẹ Láti Orílẹ̀-èdè Míì Dá Ìjọba Rọ́ṣíà Lẹ́bi Lórí Bí Wọ́n Ṣe Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Aláṣẹ Láti Orílẹ̀-èdè Míì Dá Ìjọba Rọ́ṣíà Lẹ́bi Lórí Bí Wọ́n Ṣe Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù àti ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bó ṣe ká wọn lára tó pé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí wọ́n sọ jẹ́ ká rí i pé irọ́ gbuu ni ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà sọ pé báwọn ṣe gbẹ́sẹ̀ lé ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ò lè nípa lórí òmìnira tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan ní láti ṣe ohun tó gbà gbọ́. Àmọ́ bí Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe sọ, “ohun tí wọ́n sọ ò bá ohun tí [ìjọba Rọ́ṣíà] ń ṣe mu.” Nígbà tí ìjọba Amẹ́ríkà fi ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà sọ wé ohun tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n parí èrò sí pé “ṣe ni wọ́n ń kó ọ̀rọ̀ ara wọn jẹ.”

Ọkùnrin mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ti fi sẹ́wọ̀n, àyẹ̀wò méjìlá (12) sì ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìwà ọ̀daràn ní ìlú mọ́kànlá (11). Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó jẹ́ tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba ń gbẹ́sẹ̀ lé túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tíyẹn ò sì múnú wa dùn, lájorí ohun tó ń kó ìrònú bá wa ni ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí yìí torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù àti ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ké pe ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n tẹ̀ lé àdéhùn tí wọ́n ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn, ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́.

Tẹ ìlujá yìí kó o lè ka àwọn ohun tí wọ́n sọ:

https://www.osce.org/permanent-council/381820

https://www.osce.org/permanent-council/381823