Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 2, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Sọ̀rọ̀ Lórí Bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Sọ̀rọ̀ Lórí Bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláṣẹ kárí ayé ti sọ̀rọ̀ lórí bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì sọ pé wọ́n máa jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn tí àwọn bá rí wọn tí wọ́n ń jọ́sìn lórílẹ̀-èdè náà. Ṣe làwọn èèyàn sọ̀rọ̀ sí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà láti fi hàn pé ẹjọ́ tí wọ́n dá fún àwọn ẹlẹ́sìn kékeré tó ń ṣe ẹ̀sin wọn nírọwọ́rọsẹ̀ yìí kò tọ́, ìdájọ́ náà sì ti le jù.

Ní July 17, 2017, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta ti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Rọ́ṣíà sọ pé àwọn fara mọ́ ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ ṣe ní April 20 pé kí ìjọba “fòfin de ‘Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà’ àti àwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì fa gbogbo ohun ìní wọn lé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́wọ́.” Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ ṣe yìí mú kí wọ́n fòfin de ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Lẹ́yìn Ìpinnu Tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ṣe ní July 17, 2017

Díẹ̀ rèé lára ohun táwọn èèyàn sọ lẹ́yìn ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Rọ́ṣíà ṣe ní July 17,  2017, tí wọ́n sọ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ dá ní April 20:

“Ó ká wa lára gan-an pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé ‘agbawèrèmẹ́sìn’ ni wọ́n. Ìpinnu ti ilé ẹjọ́ ṣe yìí fi hàn pé ẹ̀sùn ọ̀daràn ni wọ́n máa fi kan àwọn 175,000 tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà lórí pé wọ́n ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, èyí sì ta ko òmìnira ẹ̀sìn tí Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà fọwọ́ sí.”—Lord Ahmad of Wimbledon, Minister for Human Rights, Foreign and Commonwealth Office, ní Great Britain. https://www.gov.uk/government/news/minister-for-human-rights-statement-on-russian-supreme-court-ruling

“Ó ti ń di lemọ́lemọ́ ní Rọ́ṣíà pé kí àwọn aláṣẹ máa fúngun mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké, àmọ́ ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe lọ́sẹ̀ yìí lórí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni tuntun tá a rí gbọ́. À ń rọ àwọn aláṣẹ ní Rọ́ṣíà pé kí wọ́n pèrò dà lórí bí wọ́n ṣe fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí Ẹ̀ka Ófíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n sì dá gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké tí wọ́n ṣì ń tì mọ́lé láìtọ́ sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ ‘agbawèrèmẹ́sìn.’”—Heather Nauert, Agbẹnusọ fún Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Iṣẹ́ Ìjọba lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. https://www.state.gov/r/pa/prs/ps/2017/07/272679.htm

“Bíi tàwọn ẹlẹ́sìn yòókù, ó yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa gbádùn òmìnira láti kóra jọ ní fàlàlà láìsí pé ẹnikẹ́ni ń dí wọn lọ́wọ́, bí Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà àtàwọn ìwé àdéhùn tí ìjọba Rọ́ṣíà fọwọ́ sí lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ ṣe sọ, títí kan ohun tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé sọ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”—Agbẹnusọ fún Àjọ European Union External Action Services. https://eeas.europa.eu/headquarters/headquarters-homepage/30022/statement-spokesperson-upheld-ban-activities-jehovahs-witnesses-russia_en

“Ó ṣeni láàánú pé ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe fi hàn pé ṣe ni ìjọba ń pe àwọn tó ń lo òmìnira ẹ̀sìn wọn nírọwọ́rọsẹ̀ ní agbawèrèmẹ́sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn, ó sì yẹ kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní gbangba láìsí ìdíwọ́ kankan tàbí pé ìjọba ń ká wọn lọ́wọ́ kò.”Daniel Mark, Alága Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé ní Amẹ́ríkà. http://www.uscirf.gov/news-room/press-releases/russia-jehovah-s-witnesses-banned-after-supreme-court-rejects-appeals

“Ó ń ká mi lára gan-an pé ohun tí ilé ẹjọ́ sọ pé àwọn fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ti múlẹ̀ báyìí. A ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀. Ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí ti sọ àwọn tó ń gbádùn òmìnira ẹ̀sìn àti èrò tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí lábẹ́ òfin di ọ̀daràn.”—Gernot Erler, Alábòójútó Ẹgbẹ́ Intersocietal Cooperation With Russia, Central Asia, and the Eastern Partnership Countries, Foreign Ministry of Germany. http://www.auswaertiges-amt.de/sid_5DAC942B7DE50BCC4AFCDFC864C2E383/EN/Infoservice/Presse/Meldungen/2017/170719-Ko_RUS-Zeugen_Jehovas.html

“Ìpinnu tí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti le jù, bí wọ́n ṣe fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì fẹ́ gbá ẹ̀sìn wọn wọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ta ko òmìnira ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ bó ṣe wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 nínú ìwé Universal Declaration of Human Rights. . . . Àfi káwọn èèyàn rere látinú gbogbo ẹ̀sìn, títí kan gbogbo àwọn tó mọyì òmìnira ẹ̀rí ọkàn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.”—Dr. Katrina Lantos Swett, ààrẹ Lantos Foundation. https://www.lantosfoundation.org/news/2017/7/17/lantos-foundation-condemns-russias-outrageous-decision-to-ban-jehovahs-witnesses

Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Lẹ́yìn Ìpinnu Tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ṣe ní April 20, 2017

Kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó ṣèpinnu, ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláṣẹ ló sọ pé àwọn ò fara mọ́ ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà dá ní April 20:

“Mo ní kí Ààrẹ Vladimir Putin lo agbára tó ní láti jẹ́ káwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké tó wà níbí, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbádùn ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin.”—Chancellor Angela Merkel, nígbà tí wọ́n ń bá Ààrẹ Putin ṣèpàdé. http://uk.reuters.com/article/uk-russia-germany-putin-syria-idUKKBN17Y1JZ

“Bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tí wọ́n pe Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ní agbawèrèmẹ́sìn, tí wọ́n ní kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé e, títí kan àwọn ibi márùn-dín-nírínwó [395] tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ṣe ló mú ká máa kọminú sí ohun tójú àwọn ará Rọ́ṣíà ṣì máa rí lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn. Èyí sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ míì tó jẹ́ ká rí báwọn aláṣẹ ṣe ń ṣi òfin agbawèrèmẹ́sìn lò láti fi ṣèdíwọ́ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti òmìnira láti kóra jọ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.”—Theodora Bakoyannis àti Liliane Maury Pasquier, àwọn alárinà àjọ PACE Monitoring Committee for the Russian Federation. http://assembly.coe.int/nw/xml/News/News-View-EN.asp?newsid=6599

“Bí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe kọ̀ láti fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn yìí, àpẹẹrẹ míì ló jẹ́ pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí wọ́n tọwọ́ bọ̀ ní Moscow, ìyẹn àdéhùn OSCE [tá à ń pè ní Ètò Ààbò àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nílẹ̀ Yúróòpù]. Kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa halẹ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nírọwọ́rọsẹ̀, kò sì yẹ kí wọ́n bu owó ìtanràn kankan lé wọn tàbí kí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ sí pé wọ́n fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí, ohun tó burú jáì ni bí ilé ẹjọ́ ṣe pàṣẹ pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní tó jẹ́ ti ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mò ń retí kí wọ́n kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.”—Senator Roger Wicker, Alága Àjọ Tó Ń Rí sí Ààbò àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nílẹ̀ Yúróòpù. http://csce.emailnewsletter.us/mail/util.cfm?gpiv=2100141660.2454.614

“Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe lánàá láti fòfin de iṣẹ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ẹ̀sùn pé ‘agbawèrèmẹ́sìn’ ni wọ́n lè mú kí wọ́n máa mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀daràn torí pé wọ́n ń jọ́sìn lásán. Bíi ti gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn yòókù, ó yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbádùn òmìnira láti kóra jọ ní fàlàlà láìsí ìdíwọ́ kankan. Ó ṣe tán, Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, àwọn ìwé àdéhùn tí ìjọba Rọ́ṣíà ti fọwọ́ sí lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn òfin lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn náà fọwọ́ sí i pé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn.”—Agbẹnusọ fún Àjọ European Union External Action Services. https://eeas.europa.eu/headquarters/headquarters-homepage/24870/statement-ban-activities-jeho

“Ó ń ká mi lára gan-an bí ìjọba ṣe fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìnídìí ní Rọ́ṣíà, àwọn tó jẹ́ pé jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ wọn ni wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Ṣe ni wọ́n fẹ́ gbá àwọn èèyàn pàtàkì yìí wọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí máa ṣèpalára gan-an fún òmìnira àwọn aráàlú lóríṣiríṣi ọ̀nà.”—Michael Georg Link, Alága Àjọ OSCE Office for Democratic Institutions and Human Rights. http://www.osce.org/odihr/313561

“Ó ṣe kedere pé bí ilé ẹjọ́ ṣe fòfin de àwọn èèyàn àlàáfíà yìí torí pé wọ́n kàn ń jọ́sìn ta ko òmìnira ẹ̀sìn tí òfin fọwọ́ sí, ó sì ta ko òfin tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, èyí tí Òfin Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gan-an fọwọ́ sí. Àfi kí wọ́n yára wá nǹkan ṣe sí i.”—Professor Ingeborg Gabriel, Aṣojú OSCE Chairperson-in-Office on Combating Racism, Xenophobia, and Discrimination. http://www.osce.org/odihr/313561

“Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Róṣíà pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ‘agbawèrèmẹ́sìn’. Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ yìí máa jẹ́ kí wọ́n mú àwọn 175,000 ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní ọ̀daràn lórí pé wọ́n ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, ó sì ta ko òmìnira ẹ̀sìn tí Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé àwọn aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ìjọba ilẹ̀ United Kingdom ń rọ ìjọba Rọ́ṣíà pé kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti fọwọ́ sí lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé pé àwọn ò ní dí àwọn aráàlú lọ́wọ́ òmìnira wọn.”—Baroness Joyce Anelay, Mínísítà Ìjọba tẹ́lẹ̀ fún Àjọ Commonwealth and the UN at the Foreign and Commonwealth Office. https://www.gov.uk/government/news/minister-for-human-rights-criticises-russian-supreme-court-ruling-for-labelling-jehovahs-witnesses-as-extremist

Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Ò Fara Mọ́ Ẹjọ́ Tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Dá

Ní July 20, 2017, Ìgbìmọ̀ Permanent Council ti àjọ OSCE fa ọ̀rọ̀ kan yọ látinú ohun tí Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn Ìgbìmọ̀ EU) sọ. Ṣe ni wọ́n ń rọ ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà pé kí wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti máa “gbádùn òmìnira láti kóra jọ láìsí ìdíwọ́ kankan, bí Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe fọwọ́ sí i, tí àwọn àdéhùn tí ìjọba Rọ́ṣíà tọwọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn òfin tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn náà sì ṣe fọwọ́ sí i.” Gbogbo àwọn ìjọba ilẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tó wà nínú ìgbìmọ̀ EU ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe nílùú Vienna, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè míì tí wọn ò sì sí nínú ìgbìmọ̀ yìí, bíi Ọsirélíà, Kánádà àti Nọ́wè náà sọ pé àwọn fara mọ́ ọn. https://eeas.europa.eu/sites/eeas/files/pc_1155_eu_jehovahs_witnesses_in_russia.pdf

Ó dun àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé gan-an pé ìpinnu tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe yìí ti mú kí ìjọba fòfin de ìjọsìn wọn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ohun táwọn iléeṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláṣẹ kárí aye sọ ti jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo ayé pé ohun tí kò tọ́ ni ilé ẹjọ́ ṣe bí wọ́n ṣe pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní “agbawèrèmẹ́sìn”, tí wọn ò sì tẹ̀ lé òfin táwọn fúnra wọn ṣe àtàwọn ìwé àdéhùn tí wọ́n ti fọwọ́ sí lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé pé àwọn máa jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ò tíì gbọ́ sí ọ̀rọ̀ yìí, a sì ń retí pé tí wọ́n bá gbọ́ sí i, wọ́n máa fagi lé ohun tí ilé ẹjọ́ sọ pé àwọn fòfin dè wá.