MAY 1, 2018
RỌ́ṢÍÀ
Àwọn Aláṣẹ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Fẹ́ Gbẹ́sẹ̀ Lé Ilé Tó Jẹ́ ti Àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
ÌLÚ NEW YORK—Ní Thursday, May 3, 2018, Ilé Ẹjọ́ Saint Petersburg máa gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá tẹ́lẹ̀ pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn àtijọ́ ní Rọ́ṣíà. Tí ilé ẹjọ́ ò bá gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí wọlé, ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ilé ńlá mẹ́rìnlá (14) tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà gba ilẹ̀ tó tó éékà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), owó ilé náà àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìlélọ́gbọ̀n (32) owó dọ́là.
Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Sestroretskiy kọ́kọ́ dá ẹjọ́ náà ní December 2017, ṣe ni adájọ́ fọwọ́ rọ́ ẹ̀rí kan sẹ́yìn, ìyẹn pé àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania (ìyẹn WTPA) tó wà ní Amẹ́ríkà tí kì í ṣe àjọ tó ń pawo wọlé ló ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àtọdún 2000 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ti sọ ilé náà di ti àjọ WTPA, àtìgbà yẹn ni àjọ WTPA sì ti san owó orí tó tó mílíọ̀nù mẹ́ta owó dọ́là fún ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fọwọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe lábẹ́ òfin yìí láti ọdún mẹ́tàdínlógún (17) sẹ́yìn, ohun tí ilé ẹjọ́ ń sọ báyìí ni pé ìwé tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi sọ ilé náà di ti àjọ WTPA ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Wọ́n wá sọ pé àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ iṣẹ́ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́síà ló ni ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòfin de àjọ yẹn lọ́dún 2017, tí ilé ẹjọ́ ò bá lọ gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí pè yìí wọlé, a jẹ́ pé ohun tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ ló máa ṣẹlẹ̀, ìjọba sì lè gbẹ́sẹ̀ lé ilé náà lójú ẹsẹ̀.
Wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ náà ní aago mọ́kànlá ààbọ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Saint Petersburg, ul. Basseynaya, 6, St. Petersburg, ní Rọ́ṣíà.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000