APRIL 3, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Fídíò: Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ò Fara Mọ́ Bí Àwọn Aláṣẹ Ṣe Fẹ́ Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
Ní April 5, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ máa pinnu bóyá wọ́n máa fagi lé orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbo ibi tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ilé ẹjọ́ bá dá àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́bi, wọ́n máa fòfin de ẹ̀sìn wọn, wọ́n á sì mú wọn ní ọ̀daràn. Oríṣiríṣi àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìrẹ́jẹ táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń hù, wọ́n tún sọ pé tí wọ́n bá fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn nìkan kọ́ ló máa ṣàkóbá fún, ó máa nípa lórí orúkọ ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà káàkiri ayé àti òmìnira ẹ̀sìn táwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní.
Heiner Bielefeldt: “Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, a jẹ́ pé gbogbo wa ni agbawèrèmẹ́sìn nìyẹn.”
Aṣojú Pàtàkì Tẹ́lẹ̀ fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Lórí Ọ̀rọ̀ Òmìnira Ẹ̀sìn àti Ohun Téèyàn Gbà Gbọ́
Richard Clayton, QC: “Nǹkan burúkú gbáà ni bí wọ́n ṣe lo òfin tí kò tọ́ yìí láti fi ṣe ohun tó burú jáì.”
Agbẹjọ́rò Tó Ń Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Kárí Ayé àti Aṣojú Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní Àjọ Ìlú Venice
Dr. Massimo Introvigne: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe oníwà ipá rárá. Àwọn gan-an làwọn èèyàn máa ń hùwà ipá sí.”
Ọ̀mọ̀wé Nípa Ohun Tó Ń Lọ Láwùjọ àti Aṣojú Tẹ́lẹ̀ fún Àjọ OSCE Lórí Ọ̀rọ̀ Gbígbógun Ti Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
Annika Hvithamar: ‘Tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, a jẹ́ kì í ṣe àwọn nìkan, ó tún kan ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó jẹ́ Kristẹni nìyẹn.’
Ọ̀jọ̀gbọ́n/Ọ̀mọ̀wé, Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Oríṣiríṣi Àṣà Ìbílẹ̀ àti Àgbègbè, ní University of Copenhagen
Lyudmila Alekseyeva: “Wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni; lójú tèmi, ìwà ọ̀daràn nìyẹn.”
Alága Ẹgbẹ́ Moscow Helsinki Group, Ara Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bá Ààrẹ Ṣiṣẹ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Aráàlú àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà
Anatoly Vasilyevich Pchelintsev: “Ẹ jẹ́ ká gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!”
Ọ̀gá Oníròyìn fún Ìwé Ìròyìn Ẹ̀sìn àti Òfin
Vladimir Vasilyevich Ryakhovskiy: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń kọ́kọ́ forí kó o, kó tó wá kan gbogbo èèyàn”
Ara Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bá Ààrẹ Ṣiṣẹ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Aráàlú àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà
Maksim Shevchenko: “Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yìí ta ko ohun tí òfin sọ lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀rí ọkàn.”
Ààrẹ fún Ẹ̀ká Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ẹ̀sìn Àti Ìṣẹ̀lú Lóde Òní
Dr. Hubert Seiwert: ‘Kò sóòótọ́ kankan nínú gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílé ẹjọ́.’
Onímọ̀ Nípa Ẹ̀kọ́ Ìsìn ní University of Leipzig
Mercedes Murillo Muñoz: “Ìjọba fọkàn tán ẹ̀sìn yìí gan-an.”
Ọ̀mọ̀wé Nípa Òfin Ṣọ́ọ̀ṣì ní University of King Juan Carlos (ní Spain)
Consuelo Madrigal: “Mi ò ka [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] sí èèyàn tó léwu rárá.”
Agbẹjọ́rò, àti Agbẹjọ́rò Àgbà Tẹ́lẹ̀ ní Spain