Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 16, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Máa Tó Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbọ́ Ẹjọ́ Dennis Christensen

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Máa Tó Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbọ́ Ẹjọ́ Dennis Christensen

Tó bá di February 19, 2018, ilé ẹjọ́ máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen. Ọmọ ilẹ̀ Denmark ni Ọ̀gbẹ́ni Christensen, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, àtìgbà tí wọ́n sì ti mú un ní May 2017 ni wọ́n ti fi sí àtìmọ́lé nílùú Oryol lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Ní January 31, 2018, Igbákejì Agbẹjọ́rò Àgbègbè Oryol Region kọ̀wé olójú ìwé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] mọ́ Ọ̀gbẹ́ni Christensen láti fẹ̀sùn kàn án. Agbẹjọ́rò yìí sọ pé ó jẹ̀bi ohun tó wà ní Àpilẹ̀kọ 282.2(1) nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe, èyí tó sọ pé kò bófin mu kí èèyàn ṣètò ìjọsìn lórúkọ ẹ̀sìn tí ìjọba ti kéde pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Ìyà tó le jù téèyàn lè jẹ torí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni kó ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá.

Ọ̀gbẹ́ni Christensen kì í ṣe ọ̀daràn. Ibi tí òun àti ìyàwó ẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn ti ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n ti mú un. February 19, 2018 ni ìgbéjọ́ náà máa bẹ̀rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol, ní aago méjì ààbọ̀ ọ̀sán.