Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 29, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Èèyàn Ń Ti Dennis Christensen Lẹ́yìn Kárí Ayé

Àwọn Èèyàn Ń Ti Dennis Christensen Lẹ́yìn Kárí Ayé

Arákùnrin Dennis Christensen ti lo ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (525) ọjọ́ lẹ́wọ̀n torí pé ó ń ṣe ohun tó gbà gbọ́, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) ìgbà tó ti fara hàn nílé ẹjọ́. Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol ní Rọ́ṣíà, tó ń gbọ́ ẹjọ́ Dennis, ti ṣètò ìgbẹ́jọ́ náà sí àárín oṣù December. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọdún kan ààbọ̀ tí Dennis ti wà ní àtìmọ́lé, síbẹ̀ ó ṣì ń láyọ̀, ó sì gbà pé nǹkan á dáa. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń gbọ́ àìmọye àdúrà tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ń gbà nítorí arákùnrin yìí, ó sì ń fún un lókun.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún káàdì àtàwọn ìwé tí wọ́n yàwòrán sí ni Dennis ti rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiẹ̀ ní Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n ń fìyẹn sọ fún un pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, gbágbáágbá làwọn sì wà lẹ́yìn rẹ̀. Níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe ní October 30, Dennis fi díẹ̀ lára àwọn káàdì àtàwọn àwòrán táwọn ọmọdé fi ránṣẹ́ sí i han àwọn èèyàn látinú ẹ̀wọ̀n onígíláàsì táwọn aláṣẹ dé e mọ́, kí gbogbo àwọn tó bá wá kí i lè rí i, kó sì fún wọn níṣìírí.

Lásìkò ìsinmi ní October 30, 2018, tí ilé ẹjọ́ ń gbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen, ó ń fi díẹ̀ lára àwọn lẹ́tà ìṣírí táwọn ará fún un han àwọn èèyàn látinú ẹ̀wọ̀n onígíláàsì tí wọ́n dé e mọ́.

Kì í ṣe ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nìkan lọ̀rọ̀ Dennis ń ká lára, àwọn ẹlòmíì káàkiri ayé pàápàá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní July 21, 2017, Iléeṣẹ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tó fìkàlẹ̀ sílùú Moscow kéde pé àwọn olóṣèlú ló fi Dennis sẹ́wọ̀n. Ní June 20, 2018, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà sọ pé kí Ọ́fíìsì Olùpẹ̀jọ́ Ìjọba ṣèwádìí bóyá ó bófin mu láti máa fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nígbà tó tún di September 26, 2018, Àjọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé forúkọ Dennis sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n torí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ gbà gbọ́.”

Gbangba ni ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti sọ ọ́ nílé ẹjọ́ pé báwọn ṣe gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn ò túmọ̀ sí pé àwọn máa dí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ kó má ṣe ohun tó gbà gbọ́. Àwọn agbófinró ìjọba ìbílẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀ ò tẹ̀ lé ohun tí ìjọba sọ yẹn, wọ́n sì ti ṣi òfin lò kí wọ́n lè mú Dennis àti ọ̀pọ̀ àwọn míì, kí wọ́n sì fẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” kàn wọ́n. Lọ́dún yìí, ọ̀pọ̀ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ni àwọn aláṣẹ ti ya wọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló wà lẹ́wọ̀n, àwọn méjìdínlógún (18) wà nílé, wọ́n ní wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé, àwọn míì tó sì lé ní ogójì (40) ni wọn ò jẹ́ kó lómìnira lọ́nà kan tàbí òmíì. Ohun tó bá tẹ̀yìn ìgbẹ́jọ́ Dennis yọ ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tí wọ́n lé ní àádọ́rùn-ún (90), tí wọ́n wà láwọn àgbègbè tó tó ọgbọ̀n (30) ní Rọ́ṣíà, tí wọ́n ń retí èsì ìwádìí táwọn aláṣẹ ń ṣe lórí bóyá ọ̀daràn ni wọ́n lóòótọ́.

A mọ̀ pé àwọn ará wa kárí ayé ò ní dákẹ́ àdúrà sí Jèhófà, pé kó túbọ̀ máa pèsè okun fún àwọn ará wa tí wọ́n fẹ̀sùn kàn torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kó sì máa bá wa gbé wọn ró, bí gbogbo wa ṣe ń retí ọjọ́ tó máa “mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́” fún wọn.​—Lúùkù 18:7.