Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 1, 2018
RỌ́ṢÍÀ

A Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Kí Wọ́n Má Bàa Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Àtijọ́ ní Rọ́ṣíà

A Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Kí Wọ́n Má Bàa Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Àtijọ́ ní Rọ́ṣíà

Ní Thursday, May 3, 2018, ní aago mọ́kànlá ààbọ̀ àárọ̀, Ilé Ẹjọ́ Saint Petersburg máa gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá fún wa ní December 2017 pé kí àwọn aláṣẹ gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé tá à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tẹ́lẹ̀ ní Rọ́ṣíà. Tí wọn ò bá gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè wọlé, ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ilé ńlá mẹ́rìnlá (14) tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lójú ẹsẹ̀.