JULY 21, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Àwọn Aṣojú Kárí Ayé Ti Àwọn Ará Wa ní Rọ́ṣíà Lẹ́yìn Níbi Ìgbẹ́jọ́ Tó Wáyé ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
NEW YORK—Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò pé káwọn arákùnrin láti ilẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé rìnrìn àjò lọ sílùú Moscow láti ṣojú ẹgbẹ́ ará, kí wọ́n lè jẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà mọ̀ pé gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé la wà lẹ́yìn wọn.
Nígbà táwọn aṣojú náà dé sí Rọ́ṣíà, tayọ̀tayọ̀ làwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin lọ pàdé wọn, Sàìbéríà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún làwọn kan tiẹ̀ ti rìnrìn àjò wá sí Moscow. Àwọn aṣojú náà fi dá àwọn ará ní Rọ́ṣíà lójú pé ọ̀rọ̀ wọn ń ká àwọn lára gan-an, àwọn ará kárí ayé ò sì dákẹ́ àdúrà lórí wọn. Ọ̀kan lára àwọn aṣojú náà sọ pé: “Ìgboyà táwọn ará mi ní Rọ́ṣíà ní wú mi lórí gan-an, torí wọn ò tiẹ̀ fi gbogbo ara retí pé ilé ẹjọ́ máa yí ẹjọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n dá pa dà pé àwọn fòfin de iṣẹ́ wọn.”
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ tún fi lélẹ̀ nígbà tí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tún ẹjọ́ náà gbọ́, ṣe làwọn ará ṣera wọn lọ́kan nínú ilé ẹjọ́ náà, wọ́n sì ń fìfẹ́ tòótọ́ hàn síra wọn. Ìbànújẹ́ dorí wọn kodò nígbà tí wọ́n gbọ́ bí àwọn èèyàn ṣe pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà ní gbangba bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì mọ̀ pé àdánwò ìgbàgbọ́ ló délẹ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà yìí. Síbẹ̀, báwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn nílé ẹjọ́ lọ́jọ́ yẹn, tí wọ́n sì hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ti tó láti ṣe ẹ̀rí pé irọ́ gbuu ni ẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” tí wọ́n fi kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táwọn adájọ́ tó tún ẹjọ́ gbọ́ náà fọwọ́ sí.
Mark Sanderson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ló ṣáájú àwọn ará tó rìnrìn àjò wá sí Rọ́ṣíà. Ó fìfẹ́ gbé àwọn ará ró, ó ní kí wọ́n “jẹ́ alágbára àti onígboyà” bí wọ́n ṣe ń retí àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà táwọn aṣojú yìí ń kúrò nílé ẹjọ́, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní Rọ́ṣíà ń dì mọ́ wọn, tí wọ́n sì ń sọ pé àwọn mọyì bí wọ́n ṣe wá ti àwọn lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nílẹ̀ yìí.
Àwọn aṣojú náà tún dé àwọn ọ́fíìsì aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè mọ́kànlélógún [21] tó wà nílùú Moscow kí wọ́n lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé fún wọn nípa bí inúnibíni tí àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ń ṣe yìí ṣe ń nípa lórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ń dáná sun ilé wọn, iṣẹ́ ń bọ́ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà níléèwé, wọ́n sì ń fẹ̀sùn kan àwọn alàgbà ìjọ pé wọ́n ń ṣètò ìpàdé pẹ̀lú àwọn ará wọn. Arákùnrin Dennis Christensen wà lára àwọn alàgbà yìí, ó ṣì wà látìmọ́lé di báyìí. Àwọn aṣojú náà fi fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú méjì kan tó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí ní ṣókí han àwọn aṣojú ìjọba. Ohun tí àwọn kan nínú wọn rí nínú fídíò náà ká wọn lára gan-an. Ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn aláṣẹ náà ń béèrè ni pé, ‘Ó ṣe wá jẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ Àwọn ará wa wá fìyẹn jẹ́rìí lọ́nà tó wọni lọ́kàn, wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ará wa kì í dá sí òṣèlú, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe sì ti yí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ilẹ́ Rọ́ṣíà pa dà sí rere. Aṣojú kan sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fẹ́ kẹ́ ẹ wá ọmọlẹ́yìn tiyín síwájú ni, wọn ò fẹ́ kẹ́ ẹ gba àwọn ọmọ ìjọ wọn.” Ó lé ní mẹ́wàá nínú àwọn aṣojú ìjọba náà tó rán aṣojú lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà, wọn ò sì kúrò níbẹ̀ jálẹ̀ wákàtí mẹ́jọ tí ilé ẹjọ́ fi gbọ́ ẹjọ́ náà.
Nígbà tí àwọn arákùnrin káàkiri ayé tó wá sí Rọ́ṣíà fi máa kúrò níbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ti lágbára sí i, bí àwọn ará wọn ní Rọ́ṣíà ṣe pinnu pé àwọn ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ gbé wọn ró gan-an, inú wọn sì dùn pé àwọn láǹfààní láti jẹ́rìí fáwọn aláṣẹ lọ́nà tó gbéṣẹ́.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000