JUNE 2, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Oryol Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Nípa Ọ̀gbẹ́ni Dennis Christensen
Ilé ẹjọ́ ti sún ẹjọ́ tí wọ́n ṣètò pé wọ́n máa gbọ́ tẹ́lẹ̀ ní June 7, 2017 síwájú. A ò tíì mọ ìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ọ.
Ní June 7, 2017, ní aago méjì ọ̀sán, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Oryol máa gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nípa ọmọ ilẹ̀ Denmark kan tó wà látìmọ̀lé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dennis Christensen. Ní May 25, 2017, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá wá dí àwọn ará wa lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Christensen tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Oryol.
Lórí ọ̀rọ̀ bí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ti ń ta ko òmìnira ẹ̀sìn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní látọdún yìí wá ni wọ́n ṣe fẹ̀sùn “iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn” kan àjọ tá a fi forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ìlú Oryol, tí wọ́n sì fòfin dè é ní June 2016. Ní báyìí tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ibi tá a ti forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà, àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ń sọ pé bí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Oryol ṣe ń kóra jọ láti jọ́sìn ń fi hàn pé wọn ò jáwọ́ nínú iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn tó ta ko òfin, tó mú kí ìjọba kọ́kọ́ fòfin de iṣẹ́ wọn.
Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí nípa Ọ̀gbẹ́ni Christensen, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ọ̀daràn ni torí pé ó wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àjọ tá a fi forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ nílùú Oryol, èyí tí ìjọba ti fòfin dè báyìí. Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni Christensen kò fìgbà kan jẹ́ ara ìgbìmọ̀ yìí. Wọ́n ti fi sí àtìmọ́lé báyìí, ó di July 23, 2017 kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ torí àwọn tó pè é lẹ́jọ́ sọ pé níwọ̀n bí Ọ̀gbẹ́ni Christensen kì í tí ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́síà, ó lè sá kúrò ní Rọ́ṣíà kí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò tó rí àwọn ẹ̀rí tí wọ́n lè fi ta kò ó nílé ẹjọ́.
Ní àfikún sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè nítorí bí wọ́n ṣe ti Ọ̀gbẹ́ni Christensen mọ́lé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi àwọn ẹ̀sùn tuntun yìí kún àwọn èyí tá a kọ ránṣẹ́ sí àwọn ilé ẹjọ́ gíga lágbàáyé. Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ni ojú àwọn ará wa ti ń rí màbo láwùjọ, tí wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn nítorí ìpinnu tí ijọba ṣe.