APRIL 10, 2015
RỌ́ṢÍÀ
Ẹlẹ́rìí Kan Ní Rọ́ṣíà Rí 6,000 Owó Ilẹ̀ Yúróòpù He, Ó sì Dáa Pa Dà Fẹ́ni Tó Ni Ín
ST. PETERSBURG, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Ní November 2014, Svetlana Nemchinova, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, rí àpòòwé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] owó ilẹ̀ Yúróòpù (nǹkan bí 1,360,000 náírà) ló wà nínú àpòòwé náà. Ó pẹ́ díẹ̀ kó tó rẹ́ni tó lowó náà, àmọ́ ó ṣì dá owó náà a pa dà fún un nígbà tó rí i. Wọ́n ròyìn ìwà rere tí Ms. Nemchinova’s hù yìí nínú tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìròyìn tí wọ́n gbé jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Òṣìṣẹ́ tó ń gbálẹ̀ ojú pópó ni Ms. Nemchinova ní ìlú Vologda, tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta lé nírínwó [450] kìlómítà sí àríwá ìlà oòrùn ìlú Moscow. Bó ṣe ń gbálẹ̀ lọ́wọ́, ó rí àpòòwé kan tí wọ́n ò kọ nǹkan sí lára. Bó ṣe wo inú rẹ̀, ó bá owó tabua kan nínú rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ms. Nemchinova àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò fi bẹ́ẹ̀ rí towó ṣe, síbẹ̀ ó sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ ronú pé kí n sọ owó náà di tèmi. Gbogbo ohun ti mò ń rò ni ìdààmú tí ẹni tó sọwó náà nù máa wà.”
Kí Ms. Nemchinova lè rẹ́ni tó lowó náà, ó kọ́kọ́ lẹ ìwé mọ́ ara ògiri tó wà lágbègbè náà. Nígbà tí kò sẹ́ni tó yọjú, Ms. Nemchinova gbé owó náà lọ sí báǹkì tó wà nítòsí, torí pé rìsíìtì tí orúkọ báǹkì náà wà lára rẹ̀ wà nínú àpòòwé tí owó náà. Báǹkì náà wá rí i pé Ọ̀gbẹ́ni Pavel Smirnov ló ni owó náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan láti kàn sí Ọ̀gbẹ́ni Smirnov, báǹkì náà pàpà rí ọ̀nà sọ fún un pé Ms. Nemchinova ti bá a rí owó náà.
Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Premier ti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé: “Svetlana kò rí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ohun tó ṣe. Ẹni tó ń fi tọkàntọkàn sí Ọlọ́run ni, ó sì máa ń ka Bíbélì déédéé.” Ms. Nemchinova ṣàlàyé síwájú sí i fún ìwé ìròyìn Premier pé, ohun tí òun ṣe jẹ́ nítorí pé òun máa ń tẹ̀ lé Ìlànà Pàtàkì tó wà nínú Mátíù 7:12 tó sọ pé: ‘Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.’
Ọ̀gbẹ́ni Smirnov, tó jẹ́ ayàwòrán tó ṣàwárí iṣẹ́ ọnà àkànṣe kan ti ń tọ́jú owó náà pa mọ́ kó lè fi ra irinṣẹ́ àkànṣe kan láti mú kí ìwádìí rẹ̀ nípa aró túbọ̀ tẹ̀ síwájú. Ó sọ pé: “Mi ò mọ bí mi ò bá dúpẹ́ tán lọ́wọ́ Svetlana. Ohun tí Svetlana ṣe yìí máa mú ká túbọ̀ máa fọkàn tán àwọn èèyàn. Ohun kan tó kù kí n sọ ni pé: ‘Ọlọ́run wà!’”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000
Russia: Yaroslav Sivulskiy, tẹlifóònù +7 812 702 2691